2019 Elections: Ìpínlẹ Akwa Ibom ti gbà kí Buhari lo pápá ìṣeré fún ìpolongo

Papa iṣere Uyo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn ididje ere bọọlu lorisirisi ni wọn ti gba ni aaye yi

Lẹyin ti o kọ lati yọnda ki ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lo papa iṣere Godswill Akpabio to wa ni ilu Uyo fun ipolongo ibo ni ipinlẹ Akwa Ibom, ijọba ipinlẹ naa ti fọwọ si pe ki ẹgbẹ naa tẹsiwaju lati lo papa isere ọhun.

Kọmisọna fun ọrọ ọdọ ati ere idaraya Monday Uko lo fọrọ naa lede.

Ṣaaju nijọba Ipinlẹ Akwa sọ pe ohun ko ni yọnda papa iṣere ọhun nitori pe ile-iṣẹ to mojuto papa isẹre naa ti lọ fun isinmi opin ọdun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Èpo ọwọn, sunkere-fakere ọkọ àti àwọn olósà jẹ́ ipenija lójú pópó

Amọ bayii, Kọmisọna Uko ṣalaye pe ile iṣẹ naa lati yọnda awọn oṣisẹ rẹ lati mojuto papa isere naa lẹyin ti wọn ba lo tan.

Kọmisọna fikun ọrọ rẹ pe ijọba Ipinlẹ naa kọ tẹlẹ lati jẹki wọn lo papa iṣere naa nitori o le ṣakoba fun koriko.

APC bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba Akwa Ibom lori papa iṣere rẹ

Agbẹnusọ fun APC ni ipinlẹ naa, Nkereuwem Enyongekere sọ fun BBC Pidgin pe igbesẹ ijọba lati ma jẹ ki awọn lo papa iṣere naa ko bojumu.

O sọ pe ''to ba jẹ oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu wọn (PDP) lo fẹ ẹ lo papa iṣere naa, wọn ko ni i kọ. Aarẹ Naijiria fẹ ẹ lo papa iṣere naa, ni wọn n sọ awawi oriṣiriṣi bayii."

O ṣalaye pe papa iṣere miran ti ijọba yọnda ko le gba gbogbo awọn eniyan ẹkùn Niger Delta to n bọ fun eto naa.

"A ṣi n ba wọn duna-dura lati yọnda papa iṣere naa fun wa lati gbalejo aarẹ.''

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ naa fi atẹjade kan sita lati ṣalaye idi ti ijọba ko ṣe fẹ ki Aarẹ Muhammadu Buhari ati ẹgbẹ APC lo papa iṣere naa, to le gba ọgbọ̀n ẹgbẹrun eeyan lati joko fun ipolongo.

Ninu atẹjade naa, kọmisana fun ere idaraya, Monday Uko sọ pe ti wọn ba fi lo papa iṣere naa fun eto ti kii ṣe ere idaraya, wọn ko ni le gbin koriko miran si' ko to o di pe Premier League Naijiria yoo bẹrẹ lọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2019.

Àkọlé àwòrán,

Papa iṣere Akwa Ibom wa lara awọn eleyi to gbaaye julọ ni Naijiria

Bakan naa ni ijọba sọ pe ileeṣẹ Julius Berger to n mojuto papa iṣere naa ti lọ fun isinmi opin ọdun, ti wọn ko si nile ṣi i titi di ọjọ keje, oṣu Kinni, ti wọn ba pada bẹrẹ iṣẹ.

Ati wi pe nitori awọn idi naa ni ijọba paapa ko fi ṣe eto orin Keresimesi to maa n ṣe lọdọọdun nibẹ.