Broadcasting Service of Ekiti State di ṣíṣí padà lẹ́yìn oṣù máàrùn

Ami idamọ NBC

Oríṣun àwòrán, @nbcgovng

Àkọlé àwòrán,

NBC ni ileesẹ igbohun-safẹfẹ Ekiti n hu awọn iwa to tako ofin isẹ igbohunsafẹfẹ.

Gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde Fayẹmi, ti fi ontẹ lu u pe ki ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ijọba ipinlẹ naa bẹrẹ iṣẹ pada lọjọ kinni, oṣu Kejila, ọdun 2019.

L'ọjọ kẹẹdogun, oṣu Keje ni ajọ to n mojuto isẹ igbohunsafẹfẹ ni Naijiria, National Broadcasting Commission (NBC), ti ileeṣẹ naa pa fun pe o kede esi ibo ti ajọ eleto idibo ko fọwọ si lasiko eto idibo gomina to waye lọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2018.

Gẹgẹ bi ikede kan ti ijọba ipinlẹ naa fi sita loju opo ayelujara rẹ, ṣiṣi ti ajọ NBC pada ṣi ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ọhun waye lẹyin ti igbimọ ti ijọba gbe kalẹ lati wadii awọn ohun to ṣokunfa bi wọn ṣe ti i pa, ti gomina Fayẹmi naa si da si ọrọ naa.

Oríṣun àwòrán, ekitistate.gov.ng

Amọ ṣa, lẹyin ipade ti gomina ṣe pẹlu awọn alaṣẹ ajọ NBC, ajọ naa gba lati ṣi i, ati pe wọn gbọdọ san owo itanran ti wọn bu fun wọn.

Gomina ti wa paṣẹ pe ki ọkan lara awọn ọga agba ileesẹ igbohunsafẹfẹ naa, Idowu Oguntuaṣe, di Ọga Agba fidiẹ titi ti igbesẹ yoo waye lori abọ iwadi igbimọ naa.

Àkọlé fídíò,

The seed: Àwa sì wá láti mú ẹ̀bùn fún Ọba tí a bí lónìí

Àkọlé fídíò,

Ipenija ojú kò di Ademola lọ́wọ́ láti kẹkọọ gboye

Àkọlé fídíò,

Èpo ọwọn, sunkere-fakere ọkọ àti àwọn olósà jẹ́ ipenija lójú pópó