Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù

Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù

Asisat Oshoala lo gba ami ẹyẹ obinrin to mọ bọọlu gba julọ ti BBC lọdun 2015.

Ogbontarigi atamatase agbabọọlu obinrin ọmọ Ikorodu nipinlẹ Eko naa ba BBC Yoruba sọrọ lori igbiyanju rẹ.

Asisat n gba bọọlu fun Naijiria ati orilẹ-ede China lasiko yii.

Ọpọlọpọ ami ẹyẹ ni Asiat Oshoala ti gba nidi iṣẹ ere bọọlu gbigba to yan laayo sẹyin.

Lọdun 2014, 2016 ati 2017 ni Asisat Oshoala gba ami ẹyẹ ẹlẹsẹ ayo agbabọọlu obinrin tilẹ Adulawọ.

Oun naa ni agbabọọlu obinrin ilẹ Adulawọ akọkọ ninu ikọ̀ tilẹ Gẹẹsi.

Lọdun 2014 ni Asisat Oshoala gba ami ẹyẹ ẹlẹsẹ ayò ati agbabọọlu to mi àwọ̀n jùlọ ninu idije agbaye ti àwọn agbabọọlu ti ọjọ ori wọn koi pé ogún ọdun.

Asisat gba awọn ọdọbinrin ti wọn n gbiyanju lati dide pe ki wọn tẹra mọ iṣẹ wọn, ki wọn ṣọra.

Yusuf Monsurat to jẹ ọkan lara awọn ọdọbinrin ti Asisat n kọ niṣẹ ere bọọlu gbigba fidunnu rẹ han fun BBC Yorùbá pé Asisat n gbiyanju fawọn ewe lati gbé orí wọn soke nidi iṣẹ ere bọọlu gbigba.

#BBCWFOTY