Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá sbum ẹnu àtẹ́ lu ìròyìn pé àwọn ọlọ́pàá kan sá lọ

Ọlọpa to n le awọn onijọgbọn

Oríṣun àwòrán, Rueters

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria koro oju si bi awọn ileeṣẹ iroyin kan ṣe fi iroyin sita pe ọlọpaa mẹtadinlaadọsan sa kuro ni ibudo ikọṣẹ lẹyin ti wọn gbọ wi pe Boko Haram ni wọn yoo d'ojukọ.

Iwe Iroyin Premium Times ati Punch jabọ pe 'awọn ọlọpaa adigboluja' to sa lọ ọhun jẹ ara ẹgbẹrun meji ọlọpaa ti Ọga Agba ọlọpaa, Ibrahim Idris, ṣeleri pe yoo ṣe iranlọwọ fun ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria lati d'oju ija kọ awọn agbesunmọmi ni ẹkùn Ila Oorun ariwa Naijiria.

Amọ gẹgẹ bi ohun ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa Jimoh Moshood sọ, gbogbo ẹgbẹrun meji ọlọpaa ti wọn ran lọ si ila oorun ariwa lo ti wa ni ibudo ikẹẹkọ, ti wọn si ti ṣetan lati darapọ mọ awọn ọmọ ogun lati gbogun ti Boko Haram.

''Koda, tidunnu-tidunnu ni awọn ọlọpaa naa fi darapọ mọ akanṣe iṣẹ naa. Ẹnikẹni ko sa lọ lara wọn.''

Ẹwẹ, awọn iroyin to kọkọ jade naa sọ pe ijiya to lagbara lo n duro de awọn ọlọpaa to sa lọ ọhun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Boko Haram ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ ibi ni ila oorun ariwa Naijiria

Iye ọlọpaa ti olu ileeṣẹ ọlọpa n wa fun 'ẹsun naa' ati igbẹjọ ko ti i foju han, nitori awọn ileeṣẹ iroyin kan sọ pe aadọwa, awọn miran si sọ pe mẹtadinlaadọsan ni.

Bo tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ ologun ko tii sọ ohunkohun nipa ọrọ naa, ṣugbọn iwe iroyin Premium Times fi orukọ ọlọpa mẹtadinlaadọsan sita loju opo ayelujara rẹ gẹgẹ bi awọn ti wọn n wa.

Oríṣun àwòrán, Premium Times

Oríṣun àwòrán, Premium Times

Oríṣun àwòrán, Premium Times

Oríṣun àwòrán, Premium Times

Oríṣun àwòrán, Premium Times