Alex Badeh: Àwọn agbenipa ojú pópó lásán ló paá

Alex Badeh

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Alex Badeh: Ọwọ́ ba afunra sí mejì

Ọwọ́ sìkún àjọ ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Náíjíríà tí ba àwọn ọdaràn tó pa ajagún fẹyinti ọmọogun ojú òfurufú Alex Badeh.

Awọn ọdaràn to ṣiṣẹ́ ńlá ibi yìí ní àjọ ọlọ́pàá ní wọn yóò fóju wọn han fún gbogbo oníròyìn lónìí lólú ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá nílu Abuja.

Ìwádìí náà wà láàrín ọmọogun ojú òfurufu, ọgá àgbà ọlọpàá àti ajọ ọlọ́páà ìpínlẹ̀ Nasarawa.

Àkọlé fídíò,

Ijó Bàtá ti Yorùbá gb'oríyìn ní Calabar Festival 2018

"A ti ṣe àṣeyọri lóri ọ̀rọ̀ yìí nítori àti mú àwọn afunra sí méjì tí à ó fojú wọn han lónìí ọjọbọ̀"

Ẹ ní tó bá akọròyìn Punch sọ̀rọ̀ sàlàyé pé àwọn kan tí na papa bora sùgbọ́n ọwọ́ yóò tẹ̀ wọn láìpẹ́

Gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe sọ àwọn tó wà nínú àhámọ ọlọpàá jẹ́ àwọn adigunjalè lórí títì márosẹ̀ tí won tí ń pa èèyàn tàbí jí èèyàn gbé látẹ̀yìn wá ní sùgbọ́n ẹjọ́ wọn ò dé ìwájú àwọn ọlọ́pàá nítorí wọn ò kà wọn kún ọdaràn tó léwu.

Alex Badeh kú ní alẹ́ ọjọ́ kejìdínlógún ọdún yìí lásìkò tó ń bọ̀ lati oko rẹ̀.

Nínú àwọn mẹ́ta tó wà nínú mótò náà, Badeh nìkan ní wọn pa, èyí ló mú kí àwọn ènìyàn máa ròò pé bóyá àwọn agbénipa ló ṣiṣẹ́ náà

Awọn ọ̀daràn náà gbé ọ̀rẹ́ Badeh ti wọn jọ wà nínú mótò sùgban wọn fi sílẹ̀ lẹ́yìn ti àwọn ẹbi rẹ̀ sàn owó kí wọn to túu sílẹ̀

Ẹ̀wẹ̀ àwọn ọmọ ogun mẹ́rin tó ń sọ́ọ ní wọn ni wọn wà ní kìlómità diẹ̀ sí ibi tó wà, àwọn náà ti wà ní atìmọlé báyìí