Ìdí tí mo fí di onìyàwó keji- Wòlíì Kasali
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Wòlíì Kasali sọ̀rọ̀ nípa awuyewuye pé ó lé ìyàwó rẹ̀ jáde nílé

Bi wọn ba ni ki pe eeyan to padanu oju ita wa ṣugbọn ti oju inu rẹ n rina daada wa,Woli Kasali nilu Ibadan jẹ irufẹ eeyan bẹ.

Ilumọka ajihinrere naa jẹ afọju lootọ sugbọn lọdọ awọn to jẹ ọmọ ijọ rẹ, kii ṣe afọju lasan.

Awọn to mọ ni a ma riran si awọn eeyan ti a si ma woye nipa iṣẹlẹ orisirisi lawujọ.

Iko BBC Yoruba tọ Woli Kasalai lọ lati beere ọrọ nipa iṣe rẹ ati awọn nnkan miran to fi mọ iroyin to n ja rainrain nipa oun ati iyawo rẹ ti wọn ni o le sita.

Woli Kasali ṣe ọpọlọpọ alaye to si ni kii ṣe wi pe oun mọmọ le iyawo oun jade bii kii ṣe wi pe oun fun ararẹ lo kẹru kuro nile.

''Mo kuku fẹran Bunmi daa,tori wi pe ọrọ to gun,ọrọ igbesi aaye mi lẹ n beere yen''

O salaye wi pe ko si ootọ ninu ọrọ wi pe oun da Bunmi sita pẹlu ọmọ maarun nitori orekelẹwa Dolapo Awosika.

''Dolapo Awosika ko wa gba ọkọ kankan lọwọ Bunmi.Oun ti o ba wa yatọ.Dolapo ko le ọlọmọ maruun sita,ko ba nile''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: