Sekinat Quadri ọmọ ọdún méje ajẹ̀sẹ́ to fẹ dabi Anthony Joshua

Sekinat Quadri ọmọ ọdún méje ajẹ̀sẹ́ to fẹ dabi Anthony Joshua

''O wun mi ki n di Naijiria 'Champion' bi Anthony Joshua ''

Erongba Sekinat Quadri abẹṣẹkubiojo ọmọbirin ọmọ ọdun mẹjẹ re e nilu Eko.

Papa iṣere Oworo Sports Centre ni a ti ṣe alabapade re e nibi ti oun ati awọn ajẹsẹ miran ti n gbaradi.

Nigba ti Sekinat wa ni ọmọ ọdun maarun ni oun ati Baba rẹ jijọ nasẹ lọ si papa iṣere naa ti o si ri awọn to n ja ẹṣẹ.

Àkọlé àwòrán,

Sekinat Quadri

''Mo sọ fun Mummy mi wi pe mo fẹ́ ma ja ẹṣẹ ṣugbọn wọn sọ wi pe rara. Daddy mi lo sọ wi pe ko buru''

Laarin awọn akẹgbẹ rẹ, Sekinat jẹ ọmọ to fi ọkan si ẹṣẹ jija ti ọrọ rẹ a si ma ya olukọni rẹ lẹnu.

''Mi o lero wi pe yoo ṣe daada nidi ẹṣẹ jija yi nitori ko lara pupọ.Sugbọn lati igba ti o ti bẹrẹ niṣe ni o n jọ mi loju.''