Zamfara killings: Ṣé lóòótọ́ ni ìjọba fẹ́ kéde, state of emergency, nítorí ìpànìyàn Zamfara?

Ajoku awọn ile nibi iṣẹlẹ ikọlu awọn agbebọn kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn eeyan kan n pariwo pe o tọ ki ijọba o gbe ijọba kogberegbe, state of emergency, kalẹ ni Zamfara

Gbogbo igba ti iroyin ikọlu awọn agbebọn ba waye ni ipinlẹ Zamfara ni jinijini maa nbo ọkan awọn eeyan orilẹ-ede Naijiria paapaa julọ lori awọn ẹmi ti o maa n sọnu sinu ikọlu ọhun.

Amọṣa, ohun ti o n ko jinijini bo ọkan ọpọ bayii lori ikọlu to n waye ni ipinlẹ naa ni iroyin kan ti o n lọ kaakiri pe o ṣeeṣe ki ijọba apapọ o kede ijọba kogberegbe, 'state of emergency' ni ipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi o tilẹ jẹ wi pe aarẹ lo laṣẹ ati kede ijọba kogberegbe ni ipinlẹ kan labẹ ofin orilẹede Naijiria, ijọba apapọ ko tii sọ boya lootọ ni ọrọ yii.

Kini gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe sọ?

Gomina ana ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe, gẹgẹ bi iṣe rẹ, lo kọkọ pariwo sita pe ikede ijọba kogberegbe n rugbo bọ ni ipinlẹ naa. Ninu atẹjade kan ti o fi sita lori ikanni itakurọsọ ayelujara twitter rẹ ni ọjọ ọdun keresimesi ni Fayoṣe ti kọkọ lu awo iroyin yii.

Image copyright Ayodele Fayose/Facebook
Àkọlé àwòrán Ayọdele Fayoṣe ti máa ń tako ìjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari

Ohun ti o sọ nigba naa ni wi pe ọgbọn ati lee sun eto idibo gomina ati ile aṣofin nipinlẹ naa siwaju ni ijọba fẹ da lati fi gbe ijọba naa kalẹ.

Fayoṣe ni eredi ipinnu yii ko yẹ lori bi ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ṣe faake kọri pe ko saye fun ẹgbẹ oṣelu APC lati fa oludije kalẹ fun idibo apapọ lọdun 2019 lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu APC kuna lati ṣeto idibo abẹnu rẹ lakoko ni ibamu pẹlu gbedeke ti ajọ eleto idibo naa gbe kalẹ.

"Wọn ti ta mi lolobo pe ijọba apapọ n gbeero lati sa pamọ si abẹ wahala ikọlu ati ipaniyan to n waye nipinlẹ Zamfara lati fikede ijọba kogberegbe ni ipinlẹ naa. Eyi si ni idahun rẹ si bi ajọ INEC ṣe faake kọri pe ohun ko ni gba ẹgbẹ oṣelu APC laaye lati fa oludije kalẹ fun idibo ọdun 2019 ni ipinlẹ naa."

Kini Gomina Zamfara sọ?

Nibayii, gomina ipinlẹ Zamfara funrarẹ, Abdulaziz Yari pẹlu ti wa kede ni ọjọbọ pe gba-gba-gba bayii ni oun wa lẹyin awọn to n pe ipe fun agbekalẹ ijọba kogbere ni ipinlẹ naa.

Yari ṣalaye nibi ipade kan to ṣe pẹlawọn oniroyin pe inu oun yoo dun pupọ bi aarẹ Buhari ba lee kede ijọba kogberegbe ni ipinlẹ naa.

"Mo wa lẹyin ikede ijọba kogberegbe bi o ba jẹ pe ohun ni yoo doola ẹmi awọn araalu nipinlẹ yii."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé

Eyi ti wa n fa ọpọlọpọ itakurọsọ bayii laarin awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Bi awọn eeyan kan ṣe n pariwo pe lootọ ni ki ijọba o gbe ijọba kogberegbe, state of emergency, kalẹ nibẹ.

Eleyii ti Ayọdele Fayoṣe ni o jẹ iyalẹnu pe gomina ipinlẹ kan lee maa beere fun agbekalẹ ijọba kogberegbe naa. Fayoṣe ti ni iriri ikede yii ri nitori lasiko ijọba ayọdele fayose ni aarẹ orilẹede Naijiria nigbakan ri, Oluṣẹgun Ọbasanjọ kede ijọba kogberegbe ni ipinlẹ Ekiti.

Fayoṣe nikan kọ lo n tako ikede yii, iyẹn ti o ba maa waye o.