Osun 2019: Ajàfẹ́tọ̀ọ́ gbé gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lọ sílé ẹjọ́ nítorí ìbúra

Gboyega Oyetọla n ṣebura gẹgẹ bii gomina tuntun nipinlẹ Ọṣun Image copyright Gboyega Jesuleke
Àkọlé àwòrán Ajafẹtọọ Kanmi Ajibọla kii ṣe ajeji si ijọba ipinlẹ Ọṣun lori ilana antẹle nipa ofin

Ajafẹtọ ọmọniyan kan, Kanmi Ajibọla ti gbe gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bura fun loṣu kọkanla ọdun 2018, Gboyega Oyetọla ati igbakeji rẹ, Benedict Alabi lọ si ile ẹjọ.

Ohun to tori rẹ gbe igbesẹ yi ni pe wọn ṣe ibura wọle si ipo wọn labẹ orukọ 'state of Osun' dipo 'Osun state' lasiko ti wọn ṣebura fun wọn ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2018.

Ninu iwe ipẹjọ oloju ewe mejidinlọgbọn to gbe kalẹ niwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun, to wa nilu Ileṣa, amofin Kanmi Ajibọla n fẹ ki ile ẹjọ o wọgile ibura wọle awọn mejeeji gẹgẹ bi eyi ti ko ba ofin ati iwe ofin orilẹede Naijiria mu nitori naa, o ni ko lẹsẹ nilẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi a ko ba ni gbagbe, Onidajọ Yinka Afọlabi ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun to wa ni ilu Ileṣa kan naa ti kọkọ gbe idajọ kalẹ loṣu kejila ọdun 2018 pe lilo orukọ 'state of Osun' fun ipinlẹ Ọṣun tako ofin orilẹede Naijiria.

Kanmi Ajibọla ni oun fẹ ki ileẹjọ o yannana boya labẹ ofin to da awọn ipinlẹ silẹ ati eyi to wa fun iburawọle fun awọn to dipo oṣelu mu, o lẹtọ fun gomina ipinlẹ naa lati ṣebura wọle pẹlu orukọ naa.

Image copyright @State of osun APC
Àkọlé àwòrán Ṣáajú ni ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti pàsẹ pé orúkọ 'state of Osun' tí ìjọba ń lò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun

Bakan naa lo tun n rọ ile ẹjọ naa lati dajọ boya ibura ti wọn ṣe fun gomina Oyetọla ati igbakeji rẹ lẹsẹ nlẹ labẹ ofin.

O ni ki ile ẹjọ si paṣẹ pe eto ibura wọle naa ko lẹsẹ nlẹ nitori naa ki wọn da gbogbo owo ilu ti wọn na fi ṣe aayan ayẹyẹ naa pada si aṣuwọn ijọba.

Bakan naa lo ni ki wọn da owo oṣu gbogbo ti wọn ti gba pada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé

O tun rọ ile ẹjọ lati paṣẹ fun gomina Oyetọla ati igbakeji rẹ pe wọn ko gbọdọ fi ipo wọn eyi ti wọn bura fun labẹ iṣakoso 'state of Osun' gba, tabi ya owo lorukọ 'Osun state' eyi ti o wa ninu iwe ofin Naijiria.