Nollywood: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá ọkùnrin tí ó rẹwà

Ọdunlade Adekola Image copyright Odunlade Adekola
Àkọlé àwòrán Ọdunlade Adekola

Oniruuru ni awọn oṣere tiata ni ilẹ Yoruba.

Pẹlu bi o ṣe jẹ pe eka ere ori itage lorilẹ-ede Naijiria, ti a mọ si Nollywood ni awọn onwoye ti kede gẹgẹ bii ileeṣẹ tiata ti o n goke ju lọ lorilẹ-ede agbaye, ẹka ere tiata ilẹ Yoruba, Yollywood si jẹ ọkan lara awọn ti o gbe e soke.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn oṣere yii ni a ti ri awọn ọkunrin oloṣere ti wọn jẹ ọdọ, ti aye n fẹ, ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, ti ẹwa wọn lee sọ obinrin maa pariwo 'bi eleyi o jẹ ọkọ ẹni ko saa ti jẹ ale ẹni'.

Odunlade Adekọla:

Image copyright odunlade adekola
Àkọlé àwòrán Ẹwà àwọn òṣèré ọkùnrin wọ̀nyí leè mú kí obìnrin maa pariwo 'bi eleyi o jẹ ọkọ ẹni ko saa ti jẹ ale ẹni'

Odunlade Adekọla ni a lee pe ni irawọ ti o n tan lagbo ere tiata Yoruba bayii, ko si si tọmọde tagba ti ko fẹran rẹ nitori oniruuru ipa ti o ti ko ninu awọn ere itage yala apanilẹrin ni tabi eyi to da lori iwa ọdaran. Lati igba ti o ti bẹrẹ iṣẹ rẹ, yoo ti le ni ọgọrun fidio agbelewo ti o ti ṣe.

Ọpọ awọn obinrin ni o si maa n woo gẹgẹ bi arimalee lọ ọkunrin eleyii ti o farahan ninu awọn ti o n tẹ lee lori ikanni instagram rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTsunami: Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ti Jumasil ti sọnù ni wọ́n rii padà

Gabriel Afọlayan, Gfresh

Image copyright Gabriel Afolayan
Àkọlé àwòrán Gabriel Afọlayan, Gfresh

Ọkan lara awọn ọmọ agba oṣere tiata Yoruba ti o ti doloogbe, Adeyẹmi Josiah Afọlayan, ti ọpọ mọ ni Ade Love ni Gabriel, ti ọpọ mọ si Gfresh.

Ọmọ ilu Agbamu nipinlẹ Kwara ni awọn Afọlayan. Bi o ti n kọrin naa lo n ṣe ere tiata. Bakan naa lo n ṣe aṣoju awọn ipolowo ọja gidigidi.

Ki a ma si parọ, ọpọ omidan ladugbo ni o mọ pe ọmọ daa sibẹ.

ẹkọ nipa ere itage ni Gabriel ka ni fasiti ibadan.

KunleAfọlayan.

Image copyright Kunle Afolayan
Àkọlé àwòrán Kunle Afolayan

Ko yanilẹnu rara pe Arẹmu ọmọ agba oṣere tiata Yoruba ti o ti doloogbe, Adeyẹmi Josiah Afọlayan, ti ọpọ mọ ni Ade Love naa wọ ọkan lara awọn oṣere tiata Yoruba lọkunrin ti oju wọn gunrege ti obinrin ko si lee fi oju kere nipa ti ẹwa. Idi ni pe baba wọn pẹlu nigba aye rẹ kii ṣe oburẹwa rara.

Adari ere tiata ni iṣẹ ti Kunle gbaju mọ julọ. Awọn iṣẹ gbogbo ti o si ti ṣe ni wọn maa n gbayi lorilẹede yii ati loke okun. Awọn iṣẹẹ rẹ bii October 1, CEO ati bẹẹbẹẹ lọ ti gba amiẹyẹ lorilẹede Naijiria ati loke okun.

Image copyright Presidency
Àkọlé àwòrán Kunle Afolayan pẹlu awọn adanilaraya miran lọdọ Aarẹ Buhari

Bẹẹni ko yanilẹnu nigba ti orukọ rẹ jẹyọ ninu awọn adanilaraya kaakiri orilẹede Naijiria ti aarẹ Muhammadu Buhari gba lalejo ni ọdun 2018.

Ẹrin ẹnu rẹ ati iduro rẹ jẹ eyi ti o lee mu ki abo fi akọ ti o n tẹle silẹ.

Bolanle Ninalowo.

Image copyright Ninalowo bolanle
Àkọlé àwòrán Bolanle Ninalowo

Ṣaṣa ni obinrin ti yoo ri Ọgbẹni Bọlanle Ninalowo ti ko ni ki Ọlọrun ku iṣẹ nitori ẹwa rẹ.

Iṣẹ iṣiro owo ni Ninalowo kọ ni faisiti lorilẹede Amẹrika ti o si fi ṣe iṣẹ fun ni ile ifowopamọsi ki o to tẹle ohun ti ọkan rẹ fẹ, iyẹn iṣẹ ere ori itage.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé

Fẹmi Adebayọ.

Image copyright Femi Adebayo
Àkọlé àwòrán Fẹmi Adebayọ

Ajogunba ni ere itage ṣiṣe fun Ọgbẹni Fẹmi Adebayọ. Lara awọn eekan ati opomulero to gbe fidio ṣiṣe lede Yoruba goke ni baba rẹ, Adebayọ Salami, ti ọpọ eeyan mọ si 'Bello'.

Agbẹjọro ni iṣẹ ti Fẹmi kọ jade ni fasiti ki o to gba ọna iṣẹ tiata lọ.

Eledumare pari ẹwa si ara Fẹmi pẹlu, bẹẹni ko si obinrin ti yoo pade rẹ ti yoo ni oun ko ri eniyan rara.

Muyiwa Ademọla.

Image copyright Muyiwa Ademola
Àkọlé àwòrán Muyiwa Ademọla

Ẹgan ni hẹẹ pẹlu ẹwa ti Ọlọrun fun Muyiwa Ademọla. Fasiti ibadan ni oun pẹlu ti ṣetan, o si wa lara awọn eekan agbo oṣere tiata nilẹ Yoruba ati lorilẹede Naijiria lapapọ.

Eree 'Ori' ni ọdun 2004 lo pokiki Muyiwa, lati igba naa wa ni o si ti n lọ siwaju lai kaarẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAsisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù