Shehu Shagari dágbére f'áyé

Alhaji Shehu Shagari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Alhaji Shehu Shagari

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé Aare orílẹ̀èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Alhaji Shehu Shagari ti jẹ Ọlọ́hun ní'pe.

Ọmọ ọmọ olóògbé, Bello Shagari ti kéde rẹ̀ lójú opó Twitter tirẹ̀ pé lẹ́yìn àìsàn ránpẹ́ ló kú ní ilé ìwòsàn National Hospital l'Abuja.

Àwọn olóṣelu Nàìjíríà bákan náà ti bẹ̀rẹ̀ sí ni kéde rẹ̀ tí wọ́n sì ń fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn wọn ránṣẹ́.

Oluranlọ́wọ́ fún Ààrẹ Buhari fi tirẹ̀ síta lójú opó Twitter pé "máa sinmi lọ́run Alhaji Shehu Shagari. Ki Allah kó forí jì í".

Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Bukola Saraki náà ṣadura fun ẹmi oloogbe

Ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rùn-ún ni Alhaji Shehu Shagari to fi dágbére f'áyé.

A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.