Miss Africa 2018: Àwọn nkan tó ṣẹlẹ̀ ní Miss Africa 2018, Calabar

Àwọn nkan tó ṣẹlẹ̀ ní Miss Africa 2018, Calabar Image copyright @JFriks
Àkọlé àwòrán Àwọn nkan tó ṣẹlẹ̀ ní Miss Africa 2018, Calabar

Diẹ lo ku ki eto yiyan omidan ilẹ Afrika, ikẹta iru rẹ to waye nilu Calabar lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, 2018, di nkan mi i lẹyin ti wọn kede ẹni to jawe olubori.

Omidan Dorcas Dienda, to jẹ́ aṣoju orilẹede Congo lo jawe olubori nibi eto naa.

Àrà ọ̀tọ̀ inú orin tó jáde lọ́dún 2018 ní Nàìjíríà

Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá ọkùnrin tí ó rẹwà

Ni kete ti wọn kede rẹ pe oun ni omidan tuntun fun ilẹ Afrika, to si n rin, yan fanda lori itage ni ina dede gba mọ irun ori rẹ.

Niṣe ni ina fo lati ara awọn ina igbalode ti wọn fi ma n dawọ idunnu nibi ayẹyẹ fo si i lori, ti irun rẹ si gbina.

Ṣugbọn, awọn kan lara awọn to ṣe akoso eto naa ti sọ wi pe irun agbebọ ori, wiigi, to de sori lo gbina, kii ṣe irun rẹ gan n gan.

Gomina ipinlẹ Cross River to gbelejo eto naa, Ben Ayade, sọ pe eto naa ni afojusun lati ṣafihan ẹwa ilẹ Afrika ati ohun to yẹ ki ọkunrin mọ tabi reti lati ọdọ obinrin ilẹ Afrika.

Àkọlé àwòrán Gomina Ben ayade ati ẹni to di Omidan Afrika tuntun
Image copyright Miss Africa
Àkọlé àwòrán Diẹ lara awọn oludije pẹlu asia orilẹede ẹnikọọkan wọn
Image copyright Miss Africa
Àkọlé àwòrán Ẹbun ẹgbẹrun marundinlogoji Dọla ni ẹni to bori gba pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ SUV kan

Orilẹede mẹẹdọgbọn lo kopa ninu idije naa. Congo, Sierra Leone, Ghana, Cameroon, Zambia, Burundi, South Africa, Zimbabwe, Malawi, Tunisia, Tanzania, Botswana, Angola, Uganda, Somalia, Algeria, Togo, South Sudan, Kenya, Gambia, Namibia, Rwanda, Mozambique, Morocco ati Nigeria.

Àkọlé àwòrán Àwọn oludije

Related Topics