Shehu Shagari; Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa olóògbé

Shehu Shagari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Oun ni aarẹ alagbada akọkọ ati aarẹ kan ṣoṣo to jẹ lasiko eto oṣelu awaarawa keji (1979-1983).

Wọn bi Shehu Usman Aliyu Shagari ni ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 1925, ni abule Shagari to wa ni ipinlẹ Sokoto.

O wa lati ile olorogun, oun si ni ọmọ kẹfa ti wsn bi ninu ẹbi rẹ.

Shagari bẹrẹ iwe kika nileewe ti wọn ti n kọ Keu, ko to o di pe o lọ si ileewe alakọbẹrẹ Yabo Elementary School lọdun 1931 si 1935.

Bakan naa lo lọ si ileewe Kaduna College laarin ọdun 1941 si 1944.

O gboye imọ ijinlẹ gẹgẹ bi olukọ ni nileewe giga Teachers Training College to wa ni Zaria, nipinlẹ Kaduna.

O si siṣẹ olukọ lati ọdun 1953 di 1958 ni ẹkùn Sokoto.

Àkọlé fídíò,

Tunde Kelani k'ẹdun iku Akinwunmi Ishola

Oun ni aarẹ alagbada akọkọ ati aarẹ kan ṣoṣo to jẹ lasiko eto oṣelu awaarawa keji (1979-1983).

Bakan naa lo jẹ minisita ati ọmọ igbimọ oluṣakoso ninu ijọba apapọ lẹẹmeje laarin ọdun 1958 si 1975.

Shehu Shagari darapọ mọ oṣelu lọdun 1951 lasiko to fi di akọwe ẹgbẹ Northern People's Congress ni Sokoto. O si wa ni ipo naa di ọdun 1956.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Shagari lasiko to bẹ Ọbabinrin Elisabẹti keji wo nilu London lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 1981.

Lọdun 1954, wọn dibo yan an fun igba akọkọ si ipo ọmọ ile aṣofin apapọ lati ṣoju ẹkùn idibo Iwọ Oorun Sokoto. O di akọwe fun Olotu Ijọba Nigeria nigba naa, Sir Abubakar Tafawa Balewa lọdun 1958, ko to o di pe o di minisita fun kata-kara ati ọrọ awọn ileeṣẹ lọdun 1959.

Lọdun 1959 si 1960, Shagari jẹ Minisita fun idagbasoke eto ọrọ aje. Ipo naa lo wa di ọdun 1960 ti wọn tun sọ ọ di minisita fun ọrọ awọn oṣiṣẹ fẹhinti di ọdun 1962.

Lati ọdun 1962 si 1965, Shagari wa ni ipo Minisita fun ọrọ abẹle. Ipo minisita fun akanṣe iṣẹ lo wa ti iditẹ gbajọba akọkọ fi waye ninu oṣu Kini, lọdun 1966

Lẹyin ogun abẹle to waye, Ọgagun to wa ni iṣakoso nigba naa, Yakubu Gowon, fi Shagari jẹ Kọmisana ijọba apapọ fun idagbasoke eto ọrọ aje, imupadabọsipo ati atunto laarin ọdun 1970 si 1971.

Àkọlé fídíò,

Ọmọge Campus: Lọla Alao ní Aisha ti ni àìsàn jẹjẹrẹ ti pẹ́

Ẹwẹ, o jẹ minisita fun eto ẹnawo lọdun 1971 si 1975. Lasiko yii bakan naa lo jẹ gomina fun Banki Agbaye ati ọmọ igbimọ ajọ to ayanilowo lagbaye, International Monetary Fund (IMF).

Lọdun 1978, Shehu Shagari jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ to bẹrẹ ẹgbẹ oṣelu National People's Party. Ẹgbẹ naa si yan an lọdun 1979 lati dije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọkan lara awọn eto ipolongo ibo ti shagari ṣe nigba to fẹ du ipo aarẹ Naijiria

Ninu eto idibo naa, o jawe olubori, o si di aarẹ Naijiria.

Shagari gbe apoti ibo saa ọlọdun mẹrin fun igba keji lọdun 1983, o si tun wọle.

Awọn ẹsun bi iwa ijẹkujẹ, to fi mọ ṣiṣe mago-mago lasiko eto idibo ọdun 1983 ni wọn fi kan iṣakoso Sahgari. Eyi ati bi eto ẹnawo ijọba ṣe dẹnu kọlẹ, ti ìṣẹ si pọ laarin ilu mu ki awọn araalu bẹrẹ si ni korira iṣejọba rẹ.

Ọgagun Muhammadu Buhari ja ijọba gba mọ lọwọ lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 1983.

Lasiko ti orilẹede Naijiria ri ọpọlọpọ owo latara epo bẹtiro, Shagari fi ipese ile gibgbe, kikọ ileesẹ ati idagbasoke eto irinna ati iṣẹ agbẹ ṣe afojusun ijọba rẹ.

Lọdun 1980, ijọba rẹ pari kikọ ibudo ifọpo Kaduna refinery, o si bẹrẹ iṣẹ lọdun naa. Bakan naa lo àri kikọ awọn ibi kan ni ileeṣẹ ti wọn ti n wa irin tutu ni Ajaokuta.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Gẹgẹ bi ikede ti ọmọọmọ rẹ kan fi sita, Shagari ku lẹyin aisan ra npẹ sileewosan gbogboogbo to wa nilu Abuja.

Oun kan naa lo pari ileeṣẹ to n ṣe irin, Delta Steel Complex lọdun 1982. O si tun da ilee'sẹ ti wọn ti n jo irin mọ irin, Aluminium Smelter Company of Nigeria, silẹ nilu Ikot Abasi, to wa nipinlẹ Akwa Ibom ode oni.

Iyawo mẹta ni Oloogbe Shehu Shagari fẹ: Amina, Aishatu ati Hadiza Shagari. O bi ọpọlọpọ ọmọ.

Ọkan lara awọn iyawo rẹ, Aishatu Shagari dagbere faye nileewosan kan nilu London lọjọ lẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2001 lẹyin aisan ra npẹ.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2018 ni Shehu Shagari jade laye lẹni ọdun mẹtalelaadọrun.

Gẹgẹ bi ikede ti ọmọọmọ rẹ kan fi sita, Shagari ku lẹyin aisan ra npẹ sileewosan gbogboogbo to wa nilu Abuja.