Anambra mortuary: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú jóná di eérú nínú iná tó jó ní mọ́ṣúárì Anambra

Ayẹyẹ ti wọn fi n jo oku nina ni India

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ayẹyẹ ti wọn fi n jo oku nina ni India

Ijọba ipinlẹ Anambra ti bẹrẹ eto lati da awọn oku to jona ninu iṣẹlẹ ijamba ina to waye ni mọṣuari ileewosan gbogboogbo Enugwu-Ukwu, nijọba ibilẹ Njikoka lọjọ Abamẹta.

Kọmisana eto iroyin nipinlẹ naa, Don Adinuba sọ fun BBC Yoruba pe oku bi aadọta lo jona guru-guru ninu iṣẹlẹ ina ọhun to waye ni nkan bi aago maarun irọlẹ.

O ṣalaye wi pe kọmisana fun eto ilera, Joe Akabuike ati awọn onimọ nipa ayẹwo ẹya ara ti gunlẹ si mọṣuari naa lati ṣe ayẹwo ati akọsilẹ awọn oku to jona ọhun.

Ati pe wọn yoo lo ayẹwo DNA lati tọpinpin awọn oku to jona kọja nkan ti ẹnikẹni le damọ.

Kọmisana fun eto ilera ninu ọrọ tiẹ naa sọ wi pe ''igbo kan ti wọn dana sun nitosi mọṣuari naa lo ran mọ ọ.

Ati pe nikete ti ayẹwo ba pari ni wọn yoo yọnda awọn oku fun awọn ẹbi wọn.''

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Anambra, Haruna Mohammed sọ ninu atẹjade kan pe ina ọhun ba mọṣuari naa jẹ pupọ, to si tun jo awọn oku kọja boṣeyẹ.

Àkọlé fídíò,

'Obìnrin tí kó ba fẹ́ òṣìṣẹ́ Mọ́ṣúárì, ìpinu rẹ̀ mẹ́hẹ'

O sọ pe ''ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa to n rin kiri ni agbegbe naa to sare si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, ki awọn janduku ma ba a lo anfaani naa lati jale.''

A ti wi pe nigba ti agbara awọn pana-pana ati araalu yoo fi ka ina naa, o ti ba nkan jẹ pupọ nitori pe gbogbo oku to wa nibẹ lo ti fẹ ẹ jona tan kọja nkan ti ẹnikẹni le damọ."

Amọ ṣa, Mohammed sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ti i le sọ koko nkan to fa iṣẹlẹ ina naa.