Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gbogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Òjòjò kò ni ṣowó kó má ná ọjà, ko ko ko ni ara ọta gbogbo yin a maa le.

Eyi ni ibẹrẹ adura opin ọdun ati ti ọdun tuntun ti Alapinni Ooṣa n se fun gbogbo ọmọ Kaarọ o jiire.

Bí Ọdún se n ko igba wọle, tí ọdun tuntun, 2021 wọle de wẹrẹ, ni BBC Yorùbá gbadura fún gbogbo ẹyin ololufẹ wa pe:

Yọ̀bọ̀ ti ìgbín n yọ̀ ni ki gbogbo yin máa yọ̀ jábọ́ kuro lọwọ ewu gbogbo tó wà ninu ọdun tuntun yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ganiu Nafiu ti gbogbo ololufẹ Yollywood mọ si Alapinni Ooṣa ti ṣe iwure ọdun tuntun pe ohun gbogbo ti koowa ba ti n lù si daadaa ni o maa dún tó maa dùn láti jó sí lawujọ.

Ọdun tuntun ti wọle de lagbaye, ọdun naa jẹ ọdun ireti ọpọlọpọ paapaa fun isinmi ati alaafia lori ohun gbogbo to n ṣẹlẹ kaakiri agbaye lasiko yii

Ọdun tuntun yii a dun fun gbogbo wa, eso alaafia a kari lọọdẹ koowa wa.