Logo Benz: Ọba ìlú Benin kìlọ̀ fáwọn ọ̀dọ́ lórí ṣíṣe òògùn owó òjijì.

Image copyright @adelovecom
Àkọlé àwòrán Ọba Benin ni atunbọtan oṣo ṣiṣẹ kii dara

"Awọn ọdọ ti wọn n lepa owo gbigbona nipa pipa eeyan tabi jiji awọtẹlẹ awọn obinrin ko ni ṣai foju wina atunbọtan gbigbona."

Eyi ni ọrọ ikilọ ti Ọba ilu Benin, Ọba Ewuare II gbe kalẹ nibi aṣekagba ọdun Igue to waye nilu Benin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Ninu ọrọ to sọ nibi ayẹyẹ naa, ko pamọ pe ọba alayeluwa naa n kọminu lori bi awọn ọdọ ṣe n lọwọ ninu ogun owo ṣiṣe bayii.

Ọba Ewuare II ni iwa oṣo ṣiṣẹ, yatọ si pe o ṣajeji si aṣa ati iṣe ilẹ Benin, ko si ninu iwa ati aṣa itẹwọgba ni ilẹ kilẹ lorilẹ Afirika.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTsunami: Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ti Jumasil ti sọnù ni wọ́n rii padà

O ni ki awọn ọdọ o ṣọra fun ilepa owo ojiji lai ṣiṣẹ nitoripe bopẹ boya igbẹyin rẹ kii san fun awọn to ba ṣee.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfro Brazilians: ìlú Rio ni a máa kọ ilé ìṣẹmbáyé náà sí