2019: INEC ní àwọn kò tíì gbọ́ nípa ikú aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko to kú

Aṣofin Ayeọla Abayọmi

Oríṣun àwòrán, Nigeria National Assembly

Àkọlé àwòrán,

Ileewosan aladani ni ilu Eko ni aṣofin Ayeọla dakẹ si lẹyin aisan ranpẹ

Ọkan lara awọn aṣofin to n ṣoju ipinlẹ Eko nile aṣoju-ṣofin, Abayọmi Ayeọla jade laye ni ọjọ Aiku.

Amọṣa, awọn alaṣẹ ajọ eleto idibo apapọ orilẹ-ede Naijiria, INEC ti sọ pe awọn ko tii gbọ nipa iku rẹ ati pe o di igba ti wọn ba gbọ ki wọn to mọ igbesẹ to kan lati gbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, alukoro fun ajọ eleto idibo lorilẹ-ede Naijiria (INEC), Ọgbẹni Oluwọle Uzzi ni o ni ilana ti iroyin bẹẹ maa n gba ki o to de ọdọ ajọ naa.

O ṣafikun pé: 'bi a ṣe n sọrọ yii, iroyin naa ko tii de ọdọ ajọ INEC. Koda, ẹyin gan an ní BBC ni ẹ n tufọ iku rẹ fun wa bayi."

Aṣofin Ayeọla to n ṣoju fun ẹkun idibo apapọ Ibeju Lẹkki nile aṣoju-ṣofin dagbere faye nileewosan kan nilu Eko lẹyin aisan ranpẹ.

Àkọlé fídíò,

Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣapejuwe iku rẹ gẹgẹ bii adanu nla fun ẹgbẹ oṣelu naa.

Labẹ ofin, lẹyin oṣu mẹfa, ko lee si aye fun atundi ibo mọ lawọn ẹkun idibo ti o ba padanu aṣofin wọn.

Pẹlu bi ọrọ ṣe ri yii, ọpọ lo ṣi n woye boya aye yoo si lee wa fun atundi ibo fun aṣofin miran fun ẹkun idibo Ibeju Lekki laigbagbe pe ibo apapọ si ile aṣofin apapọ yoo waye ni oṣu keji ọdun 2019.

Àkọlé fídíò,

Ṣọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀

Àkọlé fídíò,

Tsunami: Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ti Jumasil ti sọnù ni wọ́n rii padà

Àkọlé fídíò,

Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù