NCAA: A fún àwọn adarí ní ọ̀sẹ̀ méjì si láti dá wọn lóhùn

Murtala Muhammed international Airport 2

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Murtala Muhammed international Airport 2

Àpapọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ẹka irina ofurufu iyẹn NUATE ati ATSSSAN ti fagile iyansẹlodi ti wọn sọ wi pe awọn yoo gunle ni Ọjọ Keji, Osu Kini, ọdun 2019.

Alaga ẹgbẹ osisẹ National Union of Air Transport Employee (NCAA), Paul Igene ni awọn da iyansẹlodi naa duro nitori pe awọn adari ẹka eto irina ofurufu pẹtu si wọn ninu wi pe awọn ti kọ iwe ransẹ si ile-isẹ irina, pẹlu adehun wi pe awọn yoo da wọn lohun laarin osẹ meji.

Laipẹ yii ni awọn oṣisẹ labẹ asia awọn oṣiṣẹ agba fun awọn to n pese iṣẹ lẹka ofurufu, ATSSSAN ati awọn oṣiṣẹ ẹka ofurufuru Naijiria, NUATE sọ fun awọn oniroyin nipa ipinnu wọn lati bẹrẹ iyanṣẹlodi lọjọ keji, oṣu kinni, ọdun 2019.

Awọn alaga ẹgbẹ mejeeji ni o ti to ọdun mẹta ti wọn ti ṣe ìgbega lẹnu iṣẹ f'awọn ọmọ ẹgbẹ awọn to wa labẹ akoso NCAA.

Lucky Izebhokun ti o jẹ alaga ATSSSAN ati Ayodele Sofolayan ti NUATE ni o to gẹ pẹlu bi wọn ti ṣe n ko iyan awọn ọmọ ẹgbẹ awọn kere.

Wọn ni o jẹ ohun ti o kọ ni lominu bi awọn alakoso NCAA ti ṣe ma n gbe awọn eeyan wa lati ita lati wa jẹ olori le awọn ọmọ ẹgbẹ awọn ti o kun ọju oṣunwọn.

Lucky Izebhokun ni awọn yoo jọ wọya ija pẹlu NCAA ti wọn ba kọ lati ṣe igbega lẹnu iṣẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ awọn ki ọdun 2018 to pari.

Lọdun 2018, awọn oṣisẹ ẹka ọkọ ofurufu gun le iyanṣelodi kan ti ikọ BBC Yoruba si ba awọn arinrinajo sọrọ ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed l'Eko.

Àkọlé fídíò,

'Nígbà tí kò ṣeéṣe fún wa láti fò, a ó lọ́ wọkọ̀'

Àkọlé fídíò,

Ṣọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀

Ijiroro n waye lati dena iyanṣẹlodi

Iroyin ta gbo sọ wi pe awọn ti ọrọ kan lẹka yi ti n gbe igbese lati ri wi pe wọn dena iyanṣẹlodi yi ti o le mu inira ba awọn arinrinajo ofurufu ni Naijiria.

Oludari to n ri si eto iroyin Ncaa ọgbẹni Sam Adurogboye ni awọn alaṣẹ ncaa kii ṣe ajojisi awọn osiṣẹ wọn yio ati wi pe lai pe yi wọn yoo wa wọrọkọ fi sada lori oro yi.

Bakannaa ni olori awọn akoroyin ẹka ofurufu nigba kan ri, Chuks Iwelumo sọ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwanilẹnuwo pe oun ni igbagbo pe ọrọ naa yoo niyanju ki o to di gbedeke ọjọ keji osu kini ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa fẹ bẹrẹ iyanṣelodi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Àwọn arìnrìàjò ní pápákọ̀ òfúrufú MMA2

Wọn ti fi ọrọ yi to Minisita fun ọrọ ofurufu leti o si damiloju wi pe ko ni fẹ ki iyanṣelodi yi waye nitori pe yoo mu inira ba ara ilu

Chuks ni nnkan to n ṣelẹ labẹ NCAA ku diẹ kaato ati wi pe ifẹhonu han awọn oṣiṣẹ naa ko kọja ala.

''Ko si ẹni ti yoo gba ki wọn gbe ẹlomiran wa jẹ ọga le lori lati ita ti kii ṣe wi pe ko kaju oṣunwọn.Ọrọ yi ti fẹ di aṣeju ti o si yẹ ki atunto waye ni kiakia''

Àkọlé fídíò,

Afro Brazilians: ìlú Rio ni a máa kọ ilé ìṣẹmbáyé náà sí