Iléeṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà ní fídíò tó ti pẹ́ ní fídíò ọmọogun tí kò fẹ́ kojú Boko Haram

Aworan fọnran fidio ti ileeṣẹ ọmọogun tako Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Fidio naa ti n ja rainrain lori ẹrọ ayelujara

Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ti fẹsi si fọnran fidio kan to gbode lori ayelujara nibi ti ọmọogun kan ti n fapa janu lori aisi nkan ija lati koju ikọ Boko Haram.

Wọn ni kii ṣe ootọ ni ohun ti fidio naa n sọ- pẹlu alaye.

Ọgagun Sani Usman to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun ni lọdun 2014 ni fọnran fidio naa jade ati wi pe ohun ti o wa ninu rẹ kii ṣe atọna bi nnkan ti ṣe ri lasiko yi.

Ọpọ eeyan lo ti ṣe alabapin fidio naa to fi mọ oluranlọwọ fun Aarẹ ana Goodluck Jonathan Reno Omokri

Lati ọdun 2009 ni Boko Haram ti n da wahala silẹ́ lorileede Naijiria ati awọn orileede to yii ka bi Niger, Chad ati Cameroon.

Losu kọkanla, ọdun 2018, awọn ọmọ ileeṣẹ ologun Naijiria kan fifidio sita nibi ti wọn ti ni o kere tan ọgọrun ọmọogun lo padanu ẹmi wn ninu ikọlu pẹlu Boko Haram .

Wọn tun sọ ninu fidio naa wi pe awọn ko ni nnkan ija to koju oṣunwọn.

Eleyi ṣẹlẹ lẹyin igba ti ileeṣẹ ọmọogun ni awọn ti ra nnkan ija fun awọn ọmọogun Naijiria.

Boko Haram ti pa to eeyan ẹgbẹrun lọna ọgun ti wọn si ti ṣidi awọn aimọye eeyan kuro nile wọn laarin ọdun mẹjọ ti wọn ti n koju awọn ọmọogun orileede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfro Brazilians: ìlú Rio ni a máa kọ ilé ìṣẹmbáyé náà sí