Awakọ̀ àti ọmọ mẹta mọribọ nínú ìjàmbá ọkọ l'Eko

AWORAN IJAMBA ỌKỌ

Ijamba ọkọ kan ti waye loju ọna marose Eko si Ibadan lagbegbe Iyana Oworo.

Akoroyin wa ti iṣẹlẹ naa soju rẹ ni ko si eeyan kankan to padanu ẹmi ninu iṣẹlẹ naa ṣugbọn ọkọ mẹfa kolu ara wọn ninu ijamba naa

Ọkọ agbepo kan la gbo pe o ya lọ ba awọn awakọ ti o si kọlu ọkọ mẹfa loju popo.

Àkọlé fídíò,

Ijamba ọkọ le m'ẹmi lọ

Ninu awọn awakọ naa la ti ri arakunrin kan ati ọmọ rẹ mẹta ti wọn jijọ wa ninu ọkọ naa.

Orin ọpẹ ati iyin lo gba ẹnu rẹ pe ohun ati awọn ọmọ rẹ ko padanu ẹmi wọn.

Awọn oṣisẹ eleto pajawiri Lastma ti wa ni ibi iṣẹlẹ naa ti wọn si tin gbiyanju lati wọ awọn ọkọ naa kuro loju ọna.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: