Idẹnukọlẹ ìṣèjọba Amẹrika: Ọ́fíìsì Amẹrika ni Nàìjíríà ṣi ń pín ìwé ìrìnna

asia america
Àkọlé àwòrán,

Ise ti bere fun eni to ba fe gba iwe irinna

Idẹnukọlẹ ìṣèjọba Amẹrika lo nawo d'orile-ede Naijiria pẹlu bi wọn ti ṣe so iṣẹ gbogbo rọ nileeṣẹ Amerika to wa ni Naijiria lọsẹ to kọja.

Bayii ni ile iṣẹ ijọba Amẹrika to n fun arinrin ajo ni Naijiria niwe iriina ti fi léde pe iṣẹ n lọ ni pẹrẹwu nile iṣẹ wọn to wa ni Abuja ati ipinlẹ Eko.

Wọn ni ki ẹnikẹni to ba yẹ ko wa fun ifọrọwanilẹnuwo lati gba iwe irinna yọjú lasiko to yẹ.

Àkọlé fídíò,

Ìwà ipá nínú ìdílé máa ń bí ìgè àti àdùbí ni tó lè já sí ikú

Kí lo fàá ti wọn fi ti i pa tẹ́lẹ̀?

Wọn so ohun gbogbo to ni ṣe pẹlu iwe irina nileeṣẹ orileede Amerika leko ati Abuja rọ titi di igba ti wọn ba yanju idẹnukọlẹ ìṣèjọba to n ja rain lamẹrika.

A gbo pe awọn ẹka ileeṣẹ orileede Amerika nilu Eko ati nilu Abuja lọrọ yi kan.

Gẹgẹ bi ohun ti awọn oṣiṣẹ ọ́fíìsì Amẹrika ni Nàìjíríà fi sita loju opo Facebook wọn, wọn ni ohun to de ba orileede awọn losokunfa titi ile iṣẹ wọn pa .

Lati ọjọ kejilelogun oṣu kejila ọdun 2018 ni iṣejọba ni Amerika ti dẹnu kọlẹ nitori pe awọn ọmọ ile asofin kọ lati buwọlu owo ti Aarẹ Trump fẹ fi kọ ogiri ti yoo ya Amerika ati Mexico lọtọọtọ.

Ileeṣẹ orileede Amerika ni Naijiria sọ wi pe awọn yoo bẹrẹ iṣẹ pada ni kete ti wọn ba ti ribi yanju aawọ naa.

Ohun ti igbeṣẹ́ yi tunmọ si fun awọn to ba fẹ gba pali irina ni wi pe wọn yoo ni lati ṣe suuru titi di igba ti wọn ba bẹrẹ iṣẹ.

Àkọlé àwòrán,

US Embassy Abuja

Idẹnukọlẹ naa ti lapa lara wọn nilẹ Amerika pẹlu bi awọn agbaṣẹṣe ko ti ṣe riṣẹ gba ti ọpọ oṣiṣẹ ijọba ko si ribi rin irinajo nitori pe wọn ko ri owo osu gba.

Nnkan bi eeyan 420,000 lagbo wipe wọn ko ti ri owo osu gba laisun ọdun tuntun.

Àkọlé fídíò,

Ṣọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀

Àkọlé fídíò,

New year message: Buhari, Jonathan, Atiku, kí àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà