'Ọmọdé tó fẹ̀ràn sínsín èèyàn jẹ ní Ikorodu ni wá'

'Ọmọdé tó fẹ̀ràn sínsín èèyàn jẹ ní Ikorodu ni wá'

Ọpọ ìgbà ni wọn maa n múra bíi obìnrin láti sín wọn jẹ.

Awọn ọmọ iya mẹta kan ni wọn ti di asínjẹ pọnbele lori ikanni ayelujara instagram.

Muiz Sanni to dagba jù ninu wọn jẹ ọmọ ọdun mẹrinla nigba ti Fawas Sanni jẹ ọmọ ọdun méwaa ti Malik Sanni to kere julọ ninu wọn jẹ ọmọ ọdun mẹjọ

Ẹgbọn wọn agba lo maa n ba wọn dari fidio ti wọn n ya fi sin awọn agbajugbaja oloṣere jẹ lori ayelujara.

Muiz ni pe opin ọsẹ ni awọn maa n ya fidio naa ko ma lè pa ẹkọ awọn lara.

Ọpọ oju ninu ere oniṣe Naijiria bii Adesuwa, Genevive ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ti sin jẹ ti wọn fi sọ ara wọn di adẹrin-poṣonu.

Wọn sọ bi wọn ṣe bẹrẹ niwọnba ko to di nla bayii péki onikaluku bẹrẹ ohun to wuu lati ṣe lọdun 2019.

Igbesẹ kan naa lo ni lati kọkọ gbv'é, koda ki igbesẹ naa kere.

Ilu Ikorodu, nipinlẹ Eko ni Naijiria ni wọn wa.