UNICEF: ọmọ tuntun 395, 072 máa wá sáyé lagbaye lónìí

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Abiyamọ ku ọrọ ọmọ

Ajọ agbaye to n risi ọrọ awọn ọmọde, UNICEF, ni ọmọ 395, 072 ni awọn eeyan yoo bi loni ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2019 kaakiri agbaye.

Awọn odiwọn ti ajọ UNICEF fi gba pe awọn ọmọ tuntun naa a waye niyi:

India lo wa ni ipo akọkọ pẹlu ọmọ 69, 944

China ni ipo keji pẹlu ọmọ 44, 940

Naijiria ipo kẹta lagbaye, ipo kinni ni Adulawọ pẹlu ọmọ 25, 685.

Pakistan pẹlu ọmọ 15, 112.

Indonesia pẹlu ọmọ 13, 256.

Amerika pẹlu ọmọ 11, 086.

DRC pẹlu 10, 053.

Bagladesh pẹlu ọmọ 8, 428.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNew year message: Buhari, Jonathan, Atiku, kí àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà

Ironside Pernille, to jẹ adele aṣoju UNICEF ni Naijiria ṣalaye pẹ odiwọn ẹmi gigun awọn ọmọ ti wọn maa bi ni Naijiria loni ko ju ọdun marundinlọgọta.

O ni iwadii fihan pe o ṣeeṣe ki wọn ku ni 2074 nigba ti kò ri béé ni awọn orilẹ-ede mii.

Ironside ṣalaye pé ọmọ kan ninu ọmọ mẹta ti a bi ni Naijiria lo maa n ṣalaisi lataari awọn aisan to ṣee dena ni eyi ti o n mu ẹdinku ninu ẹmi gigun ba wọn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Inu ile pẹlu agbẹbi ni aboyun mii fẹran

Ajọ UNICEF parọwa pe o yẹ ki a tubọ ṣiṣe sii ni Naijiria lati din iku awọn ọmọ ọwọ ku sii lasiko yii.

Itọju oloyun, jijẹ ounjẹ aṣaraloore lai ṣe wahala tabi hílàhílo maa n jẹ ki eso inu aboyun dara.

Awọn ibi ti àwọn Alaboyun maa n fẹ bimọ si ni Naijiria:

Opọlọpọ àwọn Alaboyun Naijiria ni wọn maa n fẹ bimọ sinu ilé wọn tabi lọdọ awọn agbẹbi ladugbo tabi ki iyale wọn gbẹbi fun wọn

Nigba ti awọn mii maa n fi oyun inu wọn bí abíọ́nà nibikibi ti ọmọ ba ti mu wọn ni wọn a bii si bii opopona, ọna ọja, oko, tabi loju titi laiyọ lẹnu irin ajo silẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán loju ọna ni ọmọ ti n mu wọn
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Ọpọlọpọ àwọn Alaboyin Naijiria maa n fẹ bimọ sile ijọsin tabi ibudo adura wọn nitori awọn miran gbagbọ pe ogun ti inu ẹmi a di ṣíṣẹ́ lataari adura ti wọn ba gba si Olorun wọn.

Ajọ UNICEF sọ pataki omi tó mọ́ ni mimu fun alaboyun ati irufẹ ounjẹ to dara fun un bii èso bii ọsan, ọgẹdẹ, ibẹpẹ; ewébẹ̀ bii ẹfọ ugwu, ẹfọ tẹtẹ, ewedu, karọọti, ẹfọ gbure; ẹ̀wà, ẹja àti bẹẹ bẹẹ lọ

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Adura gbigba ni awọn alaboyun mii gbagbọ ninu ẹ

Bakan naa ni awọn alaboyun mii gbagbọ pupọ ninu awọn iya alagbo ti awọn mii n pe ni iya elewe ọmọ ati iya Ijaw.

Awọn elewe ọmọ yii ni ìrírí to pọ̀ lori oyun ninu, ọmọ bibi, ati ọmọ titọ ninu igbagbọ awọn alaboyun kan.

Ajo UNICEF gba awọn alaboyun nimọran lati lọ sile iwosan ijọba tabi ti aladani to kun oju owo ti wón ni awọn ohun eelo itọju alaboyun ati ọmọ tuntun.

Wọn ni ẹtọ ọmọ ko faaye gba ki aṣiṣe iya tabi baba maa dá ẹmi ọmọ ọwọ́ légbodò lọdun 2019.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iṣẹ nla niṣẹ abiyamọ kaakiri agbaye
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIkorodu Bois: Ko si ẹni ti a kò lè sín jẹ!

Ajọ UNICEF gba pe airitọju to peye fun awọn alaboyun lo maa n fa iku ọmọ tuntun.

Ọgbẹni Ironside gba awọn alaboyun nimọran lati maa lọ si ileewosan gidi fun itọju to peye.

O ni ọdun 2019 ni UNICEF yoo sami ọgbọn ọdun ti wọn gba abadofin ẹtọ awọn ọmọ wẹwẹ wọle lagbaye.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọmọ tuntun káàbọ̀

Bakan naa ni wọn gba awọn baale ati ẹbi alaboyun nimọran lati maa ṣe iranlọwọ fun wọn lai daamu ọkan alaboyun.

Pẹlu imọran pe ki alaboyun maa ṣe ere idaraya ti kò lera pupọ ki o le ran an lọwọ lasiko ìrọbí.