2019 Prophesies: Kíni ohun tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run sọ nípa ọdún 2019

Aworan ọdun 2019 ti awọn eeyan kan gbe lọwọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọdún 2019 ti wọlé, àwọn olórí ẹ̀sìn gbogbo si ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn fún ọdún tuntun náà.

Gẹgẹ bi iṣe bi ọdun tuntun ba ti n wọle wẹrẹ ni awọn ojiṣẹ Ọlọrun, Alufaa, Imaamu atawọn olori ẹsin gbogbo yoo maa jade pẹlu ohun ti wọn ba ni Ọlọrun ba awọn sọ.

Ti ọdun 2019 naa ko yẹ pẹlu bi awọn olori ẹsin kan ti ṣe n jade pẹlu iran ti Ọlọrun fi han wọn fun ọdun 2019.

Ọmọwe Daniel Olukọya, Alufa agba ijọ MFM

Image copyright Mfm
Àkọlé àwòrán Ọmọwe Daniel Olukọya, Alufa agba ijọ MFM

Iran mọkanlelọgbọn ni Alufa Olukọya fi sita ninu akojọpọ iran ti Ọlọrun fi han an fun ọdun 2019, eyi to dà pe ni ọdun irọrun ati alekun ọla.

Marun un pataki ninu iran ti Alufaa Olukọya gbe kalẹ fun ọdun 2019 ni:

1) Ọdun ara ọtọ ni ti o si nilo adura ọtọ.

2) Idojuti fun golayati ni orilẹede ati lagbaye.

3) Awọn aṣiri ohun ikọkọ ti eti ko gbọri yoo jade.

4) Awọn to n ṣẹṣo yoo pade wahala nla.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIkorodu Bois: Ko si ẹni ti a kò lè sín jẹ!

Fada Mbaka. Ijọ Aguda Adoration Ministry

Image copyright Rev Fr Ejike mbaka
Àkọlé àwòrán Fada Mbaka. Ijọ aguda Adoration Ministry

Ko sẹni ti ko mọ alufaa Mbaka ti ijọ Aguda, Adoration Ministry, to wa ni ilu Enugu lẹkun ila oorun Naijiria.

Ninu ọrọ asọtẹlẹ rẹ fun ọdun 2019, o ni idaamu ati iṣoro nlanla lo wa lọna fun orilẹ-ede Naijiria ni ọdun 2019.

Gẹgẹ bi o ṣe wi, irufẹ idaamu ti orilẹ-ede Naijiria yoo koju yoo jẹ eyi ti ko tii waye ri ninu itan rẹ.

Pasitọ Enoch Adeboye. RCCG

Image copyright RCCG
Àkọlé àwòrán Pasitọ Enoch Adeboye. RCCG

Alufa Adeboye ti ijọ Redeemed Christian Church of God ko fi gbogbo ẹnu sọrọ tan lori asọtẹlẹ rẹ fun ọdun 2019.

O ni ọbẹ̀ kìí mì nikun àgbà ni ati pé ọlọgbọn nikan lo le jó ilu agidigbo ti asọtẹlẹ ọdun 2019 jẹ fun Naijiria.

Ohun to sọ ni agbekalẹ iwe Ẹkun Jerimaya, ori kẹta, ẹsẹ kejilelogun ati ikẹtalelogun ninu Bibeli mimọ eyi to ka pe:

"22. Nítorí ìfẹ́ OLÚWA tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.

23. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀."

Biṣọọbu David Oyedepo, Ijọ Winners Chapel

Image copyright David oyedepo min
Àkọlé àwòrán Biṣọọbu David Oyedepo, Ijọ Winners Chapel

Ninu ọrs asọtẹlẹ tirẹ Biṣọọbu agba David Oyedepo ti Ijọ Winners Chapel ni awọn ẹri awoyanu ni yoo farahan ninu ọdun 2019.

O ni ko si ohun ti yoo damu alaafia orilẹ-ede Naijiria ati pe Naijiria ko ni foju kan itajẹsilẹ mọ, bẹẹ ni ko ni si ogun mọ nitori nnkan yoo yipada si rere fun orilẹ-ede Naijiria.

Yoruba gba pẹ ẹnu ẹni la fi n kọ meje ni ọrọ asọtẹlẹ, eyi to ba wuni lati gbà ni eeyan n gbà nibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?