Dino Melaye: Ọlọ́pàá ti fẹ́ wó ilé mi lulẹ̀ báyìí o

Sẹnetọ Dino Melaye Image copyright DINO MELAYE
Àkọlé àwòrán Sẹnetọ Dino Melaye

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni wi pe awọn ọlọpaa ti gbe apoti to n dena ibaraẹni sọrọ lori ẹrọ gunlẹ si ile Sẹnetọ Dino Melaye.

Lara awọn akọroyin to wa digbi nibi iṣẹlẹ yii lo fidi ọrọ naa mulẹ fun ile iṣẹ iroyin BBC Yoruba.

Lọjọru ọjọ keji oṣu kinni ọdun yii ni igbesẹ yii waye ni ile Dino Melaye, Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Iwọ Oorun ipinlẹ Kogi.

Awuyewuye laaarin ileeṣẹ ọlọpaa ati sẹnetọ Dino Melaye bẹrẹ lopin ọdun 2018 o si tun gbera wọ ọdun 2019.

Ninu iroyin kan to fi ṣọwọ lori ikanni ayelujara twitter rẹ ni owurọ ọjọru, Sẹnetọ melaye ni nibayii, awọn ọlọpaa ti fẹ ja ilẹkun ile ohun pẹlu ipa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lati bii ọsẹ kan sẹyin bayii lawọn ọlọpaa ti gẹgun yika ile Sẹnetọ Dino Melaye. Ohun ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria si sọ pe o fa eyi Ọlọpaa gbé àpótí adènà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ sílé Dinoni ẹsun ti wọn fi kan aṣofin naa pe o lẹdi apo pọ pẹlawọn janduku kan lati yinbọn lu ọlọpaa kan lẹnu iṣẹ rẹ ni ọdun 2018.

Bi o tilẹ jẹ pe aṣofin Dino Melaye ti sọ pe oun ko si nile lọwọ yii ati pe ni kete ti oun ba de oun yoo yọju sileeṣẹ ọlọpaa l'Abuja, awọn ọlọpaa ti faake kọri pe ko soun to jọ o ati pe awọn ko ni ṣi ẹsẹ kuro layika ile rẹ afi ti o ba jọwọ ara rẹ fawọn ọlọpaa nitori ẹsun naa.

Melaye ṣalaye lori ikanni twitter rẹ naa pe awọn oṣiṣẹ to n mojuto ọrọ ado oloro nileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, EOD ni wọn ko awọn ohun elo ti wọn yoo fi wo ẹnu iloro oun lulẹ wa.

Eyi ni ọjọ keje ti awọn ọlọpaa ti gẹgun yi ile aṣofin Dino Melaye ka.

Dino: Olúwa, ṣe sí àwọn ọ̀tá mi bí o ṣe ṣe sí Egypti

Image copyright INSTAGRAM/@DINOMELAYE
Àkọlé àwòrán Sẹnetọ Dino Melaye

Sẹnetọ Dino Melaye to n ṣoju ẹkun Iwọ Oorun ipinlẹ Kogi ni iha aarin gbungbun orilẹede yii fi ikini ọdun tirẹ ranṣẹ lati ibi ipamọ rẹ nibi to ti n gbadura pe ki Ọlọrun tu oun silẹ.

Lati ọjọ ti ọjọ kejidinlọgbọn ni awọn ọlọpaa ti taku si ẹnu ọna ile rẹ pe afi dandan ti awọn ba fi panpẹ ọba mu u.

Dino Melaye ni 'torí ọ̀rọ̀ òtótọ́ tí òun máa ń sọ ni wọ́n fi ń lépa òun.

Eyi da lori ẹsun ti wọn fi kan an pe oun ati awọn janduku rẹ tawọn ti ibọn lọwọ gbiyanju lati yin in lu ọlọpaa kan, Sajẹnti Danjuma Saliu ni ipinlẹ Kogi nigba to wa lẹnu iṣẹ rẹ ninu oṣu keje ọdun 2018.

Ẹwẹ, loju opo Twitter rẹ, Dino sọ pe oun ko bẹru ọla nitori pe ẹni to ni ọla, baba oun ni.

Lafikun Dino fiba f'Ọlọrun lede Yoruba:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIkorodu Bois: Ko si ẹni ti a kò lè sín jẹ!

Paba n bari rẹ ni pe Dino Melaye fi fidio sita loju opo Twitter rẹ kan naa ninu eyi to ti ni oun ko beerealafia fun awọn ọta oun nitori wọn ti sẹ́ Ọlọrun oun. O ni "ki Ọlọrun ṣe fun awọn ọta mi bo ṣe ṣe ni ilẹ Ijibiti nitori awọn ọmọ Isrẹli.

Agbẹnusọ awọn ọlọpaa, Jimoh Moshood sọ pe awọn ti kọ iwe si ile igbimọ aṣofin pe ki Dino Melaye wa fara han ni ile iṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ̀ Kogi lati wa dahun ẹsun rẹ ṣugbọn o kọjaalẹ.

Lọsẹ to kọja ni Sẹnet Dino ba figbe ta pe awọn ọlọpaa fẹ mu ohun ki wọn si gun oun labẹrẹ iku.

Awọn ọlọpaa naa fesi pe, irọ patapata ni. Wọn ni awọn sọ fun Dino pe bi o ba mọ pe oun ṣẹ, ko jẹwọ.