Mọrèmi: Ọọ̀ni ní láìsi Mọrèmi, kò leè sí ilẹ̀ Yorùbá

Mọrèmi: Ọọ̀ni ní láìsi Mọrèmi, kò leè sí ilẹ̀ Yorùbá

Awọn eekan ilu lọ̀kunrin ati lobinrin lo peju si ibi ayẹyẹ ifilọlẹ ere ati orin itan igbe aye akọni obinrin ilẹ Yoruba nni, Mọremi Ajansoro.

Ọọni Ile ifẹ́, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji ni, ko yẹ ka maa foju tẹ́mbẹ́lu awọn obinrin lawujọ̀, toripe wọ̀n n se bẹbẹ lati to ẹbi ati ilu wa.

Lai Muhammed, ninu ọrọ rẹ ni, kan saara si aya gomina ipinlẹ Ogun, Olufunsọ Amosun, to gbe owo kalẹ lati se onigbọwọ ere ati orin itan igbe aye Mọremi Ajansoro.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa rọ awọn ọmọ ilẹ yii lati maa gbe aṣa ilẹ wa larugẹ, nitori ọpọ ohun alumọni wa lo ti sọnu laisi ẹni ti yoo wa.

Lero ti Bọlanle Austen-Peters, to se Mọremi ninu ere naa, o gba pe itan Yoruba dun, ohun si lawọn eeyan nile ati loke okun fẹ gbọ, eyi ti yoo se afihan idamọ wa si iran miran.