Ẹbí Melaye: Ẹ̀rù ń bá wá lóri ilera Dino, ìgbésẹ̀ ọlọ́páà sì jẹ́ ìpálara fún

Dino Melaye Image copyright @Dino Melaye
Àkọlé àwòrán Dino Melaye ni ikọ́ sẹ́mìí-sẹmìí- Ebi Dino

Ile ẹjọ giga kan labuja ti fagile ẹbẹ agbejoro Sẹnetọ Dino Melaye pe ki awọn ọlọpaa kuro niwaju ile rẹ.

Idajọ yi wa ni idahun si ẹbẹ ti agbẹjọro rẹ Nkem Okoro gbe lọ si iwaju adajọ N.E Maha pe ki ile ẹjọ paṣẹ ki awọn ọlọpaa ye dun koko mọ Dino Melaye ki wọn si jẹ ki awọn mọlẹbi rẹ lanfaani ati ri.

Adajọ N.E Maha kọ lati gbọ ẹjọ lori ọrọ yi ti o si ni ohun yoo nawọ ẹjọ naa si adajọ agba lati gbe fun adajọ miran nitori pe isinmi ọdọọdun ohun yoo pari ni ọjọ kẹrin osu kini.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ ṣa bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ, tí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá si ń gbìyànjú láti mú sẹnatọ Dino Melaye si àhámọ́ wọn, àwọn ẹbi Dino ti ké gbàjare pé, ibi ti ọ̀rọ̀ ń lọ yii, ẹrú ilera Dino ń bà awọn lẹ́rù.

Lásìkò tí àbúrò Sẹnatọ Dino, Bolarinwa Moses Melaye bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lóri ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, ó sàlàyé pé àwọn ò mọ ibi ti ẹgbọ́n àwọn wà, àti pé àwọn ìgbésẹ̀ ti ọlọ́páà ń gbé le jẹ́ ìpálara fún ilera ẹgbọ́n òun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMọrèmi: Ọọ̀ni ní láìsi Mọrèmi, kò leè sí ilẹ̀ Yorùbá

Bolarinwa ní, yàtọ sí ẹgbọ́n oun, gbogbo àwọn olùgbé ilé náà ni wọn ti ti mọ ìtá, wọn fi ṣẹ́kẹ́sẹkẹ̀ sí ọwọ ẹni tó ń sọ ẹnu ọ̀nà ilé náà, àti pé, ìyá àwọn to jẹ́ aláìlera pẹ̀lú kò ri ọ̀nà wọlé.

O ni títí di àsìkò yìí, kò sí ọ̀nà láti bá ẹgbọ́n àwọn sọ̀rọ̀.

Nígbà ti àkọròyìn BBC Yoruba bèèrè nípa gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí wọn ń tẹ̀ ránṣẹ́ loju opo twitter Dino, ó sàlàyé pé kò sí àrídájú pé sẹnátọ Dino fúnra rẹ̀ ló ń tẹ jáde.

Ohùn Bolarinwa tó jẹ́ àbúrò Sẹnatọ Dino Melaye rèé:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ̀rù ń bá wá lóri ilera sẹnatọ Dino Melaye

Bákàn náà ló tun sọ fún BBC yoruba pé, ẹgbọ́n òun ni àìsàn ikọ́ sémìí-semìí ( Asthma) àti pé, kò lè dúró pẹ́ nínú ilé tí wọn ti já iná rẹ, tí wọn sì tún ti gbogbo rẹ̀ pa.

O ní ìlera sẹnatọ, jijẹ àti mimu, pẹ̀lú ìléra rẹ̀ ló jẹ àwọn lógún báyìí.