Nigeria Swearing in 2019: Kà nípa gómìnà tuntun ni Kwara

Ìlú Ilọrin ni a ti bí Abdulrahman Abdulrazaq tó jẹ́ onísòwò epo pàtàkì tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ agbẹjọ́rò pàtàkì ní àríwá Nàìjíríà.
Nínú àwọn ọmọ ìya rẹ̀ ni sínátọ̀ tó ṣe ojú Abuja nílé asòfin àgbà nígbà kan rí, Khairat Abdulrazaq-Gwadabe.
Abdulrahman jẹ́ olùdíje gómìnà Kwara kan sọsọ tí kò ní ìbaṣepọ̀ pẹ̀lú ìdílé Saraki láti ìgbà tí Nààjíríà ti padà sí ìlànà ijọba awa ara wa ní ọdún 1999.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Eléyìí le jẹ́ ọnà àtìlẹyìn fún un tàbí kó jẹ́ ìdàkejì rẹ̀ . Ọ̀rọ̀ náà wà lórí bí àwọn èèyàn Kwara bá ṣe dìbò.
Láti ìgbà tí Nàìjíríà ti padà sí ìlànà Democracy, ni Abdulrahman àti ọmọ ìya rẹ̀, Alimi Abdulrahman, ti ń gbìyànjú láti gba agbára ìṣèjọba kúrò lọ́wọ́ ìdílé Saraki.
Oríṣun àwòrán, Twitter/@RealAARahman
Ọjọ́ ti pẹ́ tí Abddulraman ti dá ilé iṣe alágbàta epo ọkọ̀, First Fuels Limited sílẹ̀, ilé iṣé náà jẹ́ gbajúmọ̀ lórí ọrọ̀ epo ọkọ̀ ní gúúsù iwò oòrùn Nàìjíríà, tó jẹ́ ilẹ̀ Yorùbá.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ onísòwò ló ti jẹ àǹfàní lára rẹ̀. Nínú wọn ni Tonye Cole, Ade Shounbi, Ade Odunsi àti Omamofe Boye àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ.
Abdulrahman ti du ipò gómìnà Kwara rí ní ọdún 2011 l'ábẹ́ àsìyá ẹgbẹ́ CPC àná, ṣùgbọ́n Abdulfatah Ahmed ti ẹgbẹ́ PDP lo di gómìná ìpínlẹ̀ náà l'ọ́dún náà.
Sugbọn ni ọdun 2019, lasiko ibo gomina to waye ni ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq jawe olubori, gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Kwara lọjọ Kẹsan, osu Kẹta.
Ọjọru, ọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣu Karun ọdun yii kanna si ni wọn bura fun gẹgẹ bii gomina alasẹ ipinlẹ Kwara.