Ìgunnukó: Àwọn Tápà gbà pé ẹni tó bá ń sin Ìgunnukó kò ní ráùn ohun rere

Ìgunnukó: Àwọn Tápà gbà pé ẹni tó bá ń sin Ìgunnukó kò ní ráùn ohun rere

Ninu irinajo ikọ BBC Yoruba si ilu Porto Novo, lọdọ ẹya Tapa, a foju se mẹrin bi wọn se n bọ orisa Igunnuko nibẹ.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ọba Tapa ni ilu naa salaye pe, orisa yii lo jẹ ti ẹya Tapa, to gbera lati Porto Novo lọ tẹdo si ilu Abẹokuta, lọ de agbegbe Dahomey.

O fidi rẹ mulẹ pe, orisa ọlọmọ ati olowo ni Iguunuko, orisa to n se ohun rere fun ilu ni.

Bi ilu ba si daru, bi ile kan ba gbona, ti wọn ba pe orisa igunnuko, ayọ yoo pada wọ inu ile naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fatimoh Gomez, Hakeem Malọmọ atawọn abọrisa igunnuko yoku gba pe, obinrin lo bi orisa igunnuko, lawọn obinrin se maa n ki i.

Wọn ni ire to wa ninu bibọ orisa Igunnuko ko nipẹkun, asa ajogunba wa ni, ko si yẹ ka gbagbe rẹ.

Wọn wa rọ gbogbo ẹya Tapa, to jẹ ẹya Yoruba lapapọ, lati maa sin orisa Igunnuko bo se yẹ.