Rashidat Fawẹhinmi: Sísọ èdè Yorùbá kò leè ba Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ lẹ́yìn odi

Rashidat Fawẹhinmi: Sísọ èdè Yorùbá kò leè ba Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ lẹ́yìn odi

Rashidat Fawẹhinmi, ninu imọran rẹ fawọn ọmọ ilẹ Kaarọ Oojire to fi oke okun se ibujoko, rọ wọn lati mase ri ede Yoruba sisọ bii ohun itiju nla.

O ni oun se akiyesi pe ọpọ ọmọ Yoruba to wa nilẹ okeere, ni kii fẹ fi Yoruba da esi pada, ti eeyan ba n ba wọn sọrọ ni ede abinibi wa.

O ni iwadi oun fi han pe, ọpọ wọn lo gbagbọ pe ti awọn ba n sọ ede Yoruba, eyi lee ba ede Gẹẹsi ti awọn n sọ jẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Rashidat, to ni ọmọ bibi ipinlẹ Ondo ni oun, ti oju kii si ti oun lati sọ ede oun ni oke okun, wa tun rọ awọn ọmọ ilẹ Oodua, lati mase fi ọwọ osi juwe ile baba wọn, ki wọn ma si sọ ile nu, tori ọmọ to ba sọ ile nu, o so apo iya kọ.

O fi kun pe, nkan ayọ ni ede Yoruba jẹ́, o si yẹ ka maa gbe e larugẹ ni, gẹgẹ bawọn ara India, China ati Germany ti n gbe ede wọn larugẹ.