Claudiah: ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi fínra fún ọpọlọpọ ọdún

Claudiah: ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi fínra fún ọpọlọpọ ọdún

'Mo korira ara mi pupọ'

Nigba ti Claudiah wà lọmọ ọdun mẹtala lo ni ijamba iná eyi to jó ojú ati ọrun rẹ.

O mẹnuba idojukọ rẹ fun BBC pé ọpọlọpọ igba ni oun ti fẹ pa ara oun lataari èébú ti awọn eeyan maa n bú oun lawujọ.

O ni awọn mii a maa bu oun pe ìpara bórabóra ni oun n lò ti o fun oun ni aawọ kalankinni yii.

Claudia sọrọ lori bi iṣẹ arinrin oge ṣe wu oun pupọ lati kekere ṣugbọn ti ijamba iná naa mu ifasẹyin wa si ki oun to gba kadara pe ti ẹ̀mí bá ṣi wà, ireti n bẹ.

O sọrọ lori irẹwẹsi ọkan to de ba oun lasiko naa.

Ni ipari, o gba awọn eniyan nimọran pe ki wọn ṣọra lori nkan ti wọn maa n sọ fun alaabọ ara nitori ironu lo maa n fa.

Claudiah ni ko sẹni to lagbara lori nkan to maa n ṣẹlẹ si eeyan ṣugbọn ìhà ti eeyan ba kọ si iṣẹlẹ pajawiri lo ṣe koko julọ.

O gba awọn ọdọ to n la iṣoro abuku ẹya ara wọn kọja ki wọn gba kadara ki wọn gbiyanju gbe igbesẹ