Coptic Christian: January 7 ni ọjọ́ àjọ̀dún kérésìmésì fún ẹ̀yà Krìstẹ́ní lágbègbè Lárúbáwá

Awọn kristẹni kan lagbegbe Larubawa Image copyright Analodu agency
Àkọlé àwòrán Ṣaaju ajọdun keresimesi yii, ọjọ mẹtalelogoji ni wọn fi n gba awẹ

Ọjọ karundinlọgbọn oṣu kejila ọdun ni gbogbo onigbagbọ maa n ṣe ajọyọ keresimesi. Ọpọ lo si ti fẹẹ gbagbe pe awọn ṣe ọdun keresimesi ti ọdun 2018, ṣugbọn ọjọ keje oṣu Kini ni awọn ẹya Kristẹni kan ti a mọ si Coptic Christians n ṣe ti wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bii iwe onka ọjọ ti atijọ, ti a mọ si Orthodox Calendar ti ṣe fi lelẹ, ọjọ keje oṣu kini ni a bi Jesu Kristi. Idi si niyi to fi jẹ pe ọjọ keje oṣu kinni ọdun ni awọn kristẹni ẹya wọnyii ni agbegbe ilẹ larubawa atawọn to wa ni orilẹede Russia ti o n tẹle iwe onka ọjọ yii maa n ṣe ajọyọ ọdun keresimesi tiwọn.

Ni orilẹede Egypt, ko din ni miliọnu mẹwa awọn eeyan orilẹede Egypt ti o jẹ Kristẹni, pupọ ninu wọn lo si jẹ ẹya Coptic Christian.

Awọn si ni ẹya kristẹni to pọ julọ lagbegbe Larubawa.

Image copyright Nurphoto
Àkọlé àwòrán Ọjọ keje oṣu kinni ni ọjọ ajọdun keresimesi wọn

Ṣaaju ajọdun keresimesi yii, ọjọ mẹtalelogoji ni wọn fi n gba awẹ lati pese ara wọn silẹ fun gbigba Kristi.

Lasiko awẹ yii, wọn ko gbọdọ jẹ ohunkohun to ba wa lati ara ẹranko. Ọjọ karundinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun ni wọn maa n bẹrẹ awẹ yii titi di ọjọ kẹfa oṣu kini ti o jẹ ọjọ aisun keresimesi tiwọn.

Related Topics