Saraki san owó oṣù òṣìṣẹ́ ní Kwara

Bukọla Saraki Image copyright Bukola saraki
Àkọlé àwòrán Ìṣòro ńlá ni sísan owó oṣù òṣìṣẹ́ jẹ́ fún ìpínlẹ̀ Kwara àti àwọn ìpínlẹ̀ gbogbo lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Aarẹ ile aṣofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnetọ Bukọla Saraki ti san owo oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ irẹpọdun ni ẹkun idibo apapọ gusu ni ipinlẹ Kwara.

Ni oṣu kejila ọdun 2018 ni Saraki ṣeleri ati san owo oṣu awọn oṣiṣẹ bẹrẹ pẹlu ijọba ibilẹ kọọkan kaakiri ẹkun idibo apapọ mẹtẹẹta to wa ni ipinlẹ Kwara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alaga ijọba ibilẹ Irẹpọdun, Muyiwa Ọladipọ lo kede rẹ ni ilu Omu aran.

"Miliọnu mẹtadinlogun o din ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira ni Saraki gbe kalẹ fun sisan awọn owo oṣu ti wọn jẹ awọn oṣiṣẹ."

Kii ṣe iroyin mọ pe ajẹẹlẹ owo oṣu oṣiṣẹ jẹ iṣoro nla ni ipinlẹ Kwara gẹgẹ bi o ṣe jẹ fun ọpọ ipinlẹ jakejado Naijiria. Gbogbo awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ni ijọba ibilẹ naa ni wọn kan sara si igbesẹ naa ni kete ni iro owo bẹrẹ si nii dun lapo awọn oṣiṣẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOrangun: Èdè àti àṣà Yorùba ní láti jọ wá lójú