Forbes 2018 list: Àwọn ọmọ Nàìjíríà dẹ́bi àdínkù tó bá owó Dangote rú Ààrẹ Buhari

Dangote Image copyright ERIC PIERMONT
Àkọlé àwòrán Pupọ ninu owo Dangote wa lati idi ọja Dangote Cement rẹ

Ilumọka oniṣowo ọmọ orileede Naijiria Aliko Dangote ṣi ni ẹni to lowo julọ nilẹ Afrika ṣugbọn o da bii wi pe adinku ti ba owo rẹ.

Iwe iroyin atigbadegba Forbes lo gbe orukọ awọn to lowo julọ lagbaye sita fun ọdun 2018 ti wọn si ni ipo kini ni Dangote wa pẹlu biliọnu mẹwa dọla o le die.

Gẹgẹ bi nnkan ti iwe iroyin naa ti sọ, Dangote padanu biliọnu mẹji dọla latari bi nnkan ko ti ṣe lọ deede lẹka Dangote Cement rẹ.

Mike Adenuga to jẹ alaṣẹ ati oludari ile iṣẹ Globacom pọnwọ le Dangote nipo keji pẹlu biliọnu mẹsan dọla.

Aje bu igba jẹ daada lọdọ tirẹ pẹlu bi owo rẹ ṣe tẹ wọn si lati biliọnu maarun le die to wa tẹlẹ lọdun to kọja si biliọnu mẹsan lọdun yii.

Amọ ṣa iyipada to de ba owo Dangote yii ti mu iriwisi wa lati ọdọ awọn ọmọ Naijiria ti awọn kan si n naka abuku si ijọba Aarẹ Buhari gẹgẹ bi igi wọrọkọ to mu adinku ba owo Dangote.

Loju opo Twitter ọrọ naa jọ bi ẹrin ṣugbọn awọn kan ni ''Sai Baba'' lo mu ki ọrọ aje Dangote dẹnu kọlẹ.

Wande Ajayi ni tiẹ sọ pe Dangote ti wọn yan gẹgẹ bi ọmọ igbimọ ipolongo idibo Aarẹ Buhari ko le dun'nu si bi owo rẹ ṣe n dinku labẹ ijọba Buhari.

O ni ''Next Level'' Buhari ko le so eso rere fun Dangote fun idi eyi ki awọn eeyan yaa tete gba Buhari sita

Ṣugbọn kii ṣe gbogbo eeyan naa lo sun ti wọn kọri si ibi kan naa.

Omotoke ati Makinde David ni kii ṣe bi Buhari ni pe adinku ba owo Dangote

Kini Forbes sọ?

Iwe iroyin Forbes mu alaye wa pe aiṣedeede eto ọrọ aje ati owo ti ko gbe pẹli lo mu ki iye awọn to lowo to to biliọnu dinku di ogun nilẹ afrika lati mẹtalelogun ti wọn jẹ lọdun to kọja.

Orukọ awọn miiran ti wọn wa ninu olowo biliọnu nilẹ Afrika to leke re e

  • Mohammed Dewji ọmọ orileede Tanzani lo kere julọ lọjọ ori pẹlu biliọnu $1.8 .
  • Isabel Dos Santos wa ni ipo kẹ́jọ pẹlu biliọnu $2.3
  • Folurunsho Alakija to wa ni ipo mọkandilogun ni biliọnu $1.1 billion-oun nikan lobirin to wa ninu wọn.