2019 elections: INEC gbé ìgbésẹ̀ méje fún ètò ìdìbò 2019 jáde

Oṣiṣẹ eleto idibo kan n yanju ọrọ idibo pẹlu awọn oludibo
Àkọlé àwòrán,

Oṣù kejì àti oṣu kẹta ọdún 2019 ni ìdìbò àpapọ̀ orílẹ̀èdè Nàìjíríà yóò wáyé.

Ajọ eleto idibo Naijiria ti gbe igbesẹ bi eto idibo yoo ṣe lọ lawọn ọjọ idibo apapọ ọdun 2019 jade.

Eto idibo apapọ orilẹede Naijiria yoo waye ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun 2019 ati ọjọ keji oṣu kẹta ọdun 2019 kan naa.

Igbesẹ meje ni ajọ INEC gbe kalẹ bayii pe eto idibo yoo maa gba lọjọ idibo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbesẹ akọkọ:

Ni kete ti o ba ti de ibudo idibo rẹ, to pẹlu awọn oludibo yooku ki o si fi ara han oṣiṣẹ idibo to ba wa nibẹ.

Kini idi eyi?

 • Oṣiṣẹ idibo naa ni yoo jẹ ki o mọ boya ibudo idibo rẹ ni o wa tabi o ti ṣina.
 • Oṣiṣẹ idibo naa ni yoo yẹ aworan rẹ wo lori kaadi idibo rẹ lati mọ boya aworan naa ba oju rẹ mu
 • Bi o ba ti yẹ ohun gbogbo to yẹ tan yoo dari rẹ si ọdọ oṣiṣẹ keji rẹ to wa ni ibudo naa.

Igbesẹ keji:

Àkọlé àwòrán,

Ọjọ kẹrìndínlógún oṣù kejì ni idibo si ipo aarẹ ati ile aṣofin apapọ

Oṣiṣẹ eleto idibo keji naa yoo beere fun kaadi idibo rẹ lọwọ rẹ

Kini idi eyi?

 • Lati yẹẹ wo lori ẹrọ idibo.
 • Yoo ni ki o tẹka sori ẹrọ naa lati mọ boya iwọ lo ni kaadi idibo naa nitootọ
 • Ninu Ẹrọ idibo yii ni ni orukọ rẹ, aworan rẹ aworan oju ika gbogbo awọn oludibo to forukọ silẹ ni ibudo idibo naa wa.

Igbesẹ kẹta:

Àkọlé àwòrán,

Ọjọ keji oṣu kẹta ni idibo si ipo gomina ati awọ̀n aṣofin ipinlẹ yoo waye

Lẹyin eyi ni yoo kan pipade oṣiṣẹ eletoi idibo miran (APO11) ti yoo tun beere fun kaadi idibo rẹ

Kini idi eyi?

 • Lati mọ boya orukọ rẹ atawọn iroyin gbogbo to yẹ nipa rẹ wa ninu iwe orukọ awọn oludibo fun ibudo idibo naa.
 • Oṣiṣẹ eleto idibo yii yoo sami si orukọ rẹ ninu iwe naa, yoo si da kaadi idibo rẹ pada fun ọ.
 • Yoo ta ọda ikọwe kan si ori ika rẹ lati ṣe afihan pe o wọn ti ṣe ayẹwo fun ọ lati dibo. (Bi orukọ rẹ ko ba si ninu iwe orukọ awọn oludibo naa, ko ni si aaye fun ọ lati dibo).

Igbesẹ kẹrin:

Àkọlé àwòrán,

Ajọ INEC ti ni gbogbo eto ni awọn n ṣe fun aṣeyọri idibo 2019

Yoo kan oṣiṣẹ eleto idibo to jẹ alamojuto eto idibo ni ibudo naa, (PO)

Kini iṣẹ tirẹ?

 • Yoo fi ontẹ lu ẹyin iwe idibo ti o fẹ fi dibo.
 • Yoo buwọ luu lẹyin ki o to fi le ọ lọwọ.
 • Oun ni yoo wa dari rẹ lọ si inu kuulu idibo ki o lee di ibo rẹ ni bonkẹlẹ.

Igbesẹ karun:

Àkọlé àwòrán,

Igbesẹ meje ni ajọ INEC gbe kalẹ lori eto idibo ọdun 2019

Wọn yoo fun ọ ni ọda itẹka kan ninu eyi ti oo ti ika rẹ bọ lati tẹka si aaye ti wọn fi silẹ fun oludije/ẹgbẹ oṣelu ti ọkan rẹ fẹ.

Ka iwe idibo naa gẹgẹ bii alamojuto eto ibo (PO) ṣe kaa fun ọ.

Igbesẹ kẹfa:

Lẹyin eyi, fi kuulu idibo naa silẹ ki o si ju iwe idibo naa silẹ sinu apoti ibo loju gbogbo awọn eeyan to wa nibẹ.

Skip Twitter post, 1

End of Twitter post, 1

Igbesẹ keje:

Ni bayii, o lee wa fi ibudo idibo silẹ tabi ki o duro ṣugbọn lai fa wahala rara titi di asiko ikede esi idibo.

N.B. wọn yoo lẹ esi esi idibo ibudo kọọkan si ibi to yẹ ni ibudo idibo naa fun gbogbo awọn eeyan lati rii.