Dino Melaye sun ìta gbangba mọ́jú ní ọgbà DSS
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọlọ́pàá gbé Dino lọ sí àgọ́ Ọlọ́pàá kògbéregbè SARS

Awọn ọlọpaa ti gbe Sẹnẹtọ Dino Melaye to n ṣoju ẹkun Iwọ Oorun ipinlẹ Kogi nile aṣofin agba kuro lagọ ajọ DSS.

Ọlọpaa gbe Dino lọ si ọgba awọn ọlọpaa kogberegbe SARS to wa ni agbegbe Guzape ni ilu Abuja.

Aburo Sẹnẹtọ Dino Melaye, ti ni ọlọla ati olowo ti iya ohunkohun ko lee jẹ ni awọn aṣofin lorilẹede Naijiria, amọ ti ọrọ ko ri bẹẹ fun Sẹnẹtọ Dino Melaye.

Moses Melaye lasiko to n ba BBC Yoruba Sọrọ wi pe pẹlu gbogbo owo ati ọla ti ẹgbọn oun ni, ita gbangba ninu otutu ni o sun ni alẹ Ọjọ Ẹti, Ọjọ kọkanla, Oṣu Kini, ọdun 2019 mọjumọ Ọjọ Abamẹta.

Eyi waye lẹyin to faake kọri pe oun ko lee wọ ileewosan DSS tori oun ko ni nkankan ṣe plu wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ko si si idi meji ju bi awọn ọlọpaa ti ṣe fi agidi gbee kuro ni ileewosan ọlọpaa ti o wa tẹlẹ nibi ti o ti n gba itọju lọ si ileewosan tawọn agbofinro DSS ni ilu Abuja, ṣugbọn ti aṣofin agba naa fi aake kọri pe oun ko ni wọle sinu ile iwosan naa.

"Ita gbangba ni sẹnetọ Dino sun mọju ninu ẹfọn ati otutu. Laarọ yii ni wọn tun wa gbee lọ si ileeṣẹ ọlọpaa SARS nilu Abuja."

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe awọn ọlọpaa ko tii da ina ile Sẹnetọ Melaye ti wọn ja pada eleyi ti o n mu igbe aye nira fun awọn eeyan yooku ti wọn n gbe ninu ile naa.