Ọlọ́pàá Ekiti: A kò lé sọ bóyá olósèlú ló ní ọkọ̀ ńlá tó kó ìrẹsì

Ekiti Image copyright Sunkanmi Ogunmuko
Àkọlé àwòrán Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà sojú rẹ̀ ní ìjánnú ọkọ̀ ló da isẹ́ sílẹ̀ tó sí yawọ ọjà tí ọ́pọ̀ ẹ̀mí ba ìsẹ̀lẹ̀ náà.

Igbakeji gomina ni ipinle Ekiti, Adebisi Adegboyega Egbeyemi lorukọ gomina ti se abẹwo si awọn ti wọn farapa ninu ijamba ọkọ naa.

O ni gomina Kayode Fayemi o si nile ni o ṣe ran oun lati wa wo ohun to ṣẹlẹ, o si ṣeleri pe ijọba yoo san owo itọju awọn to wa nile iwosan bẹẹ si ni yoo tun ọja naa ṣe.

Ileesẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti ti ni eniyan mejila lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ to waye ni alẹ Ọjọ Satide ni ipinle Ekiti, ti ọpọlọpọ si farapa.

agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa naa, Caleb Chukwu lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni, ọkunrin mẹfa ati obinrin mẹfa lo ku ninu isẹlẹ naa loju ẹsẹ.

Eyi waye nigbati ọkọ naa ya lọ kọlu ọkọ ayọkẹlẹ kan, ọkọ Akọta kekere ati ile to wa ni iwaju agbeegbe ọja Iworoko ni ipinlẹ Ekiti.

Image copyright Sunkanmi Ogunmuko
Àkọlé àwòrán Amọ awọn miran sọ wi pe awọn ti o ku ninu isẹlẹ naa ju bi o se yẹ lọ, ati wi pe idile wa ninu awọn to padanu ẹmi wọn.

Lori ẹsun wi pe oloselu lo ni iresi to wa ninu ọkọ naa, Chukwu ni awọn ko lee sọ pe bi ọrọ naa se ri niyẹn, sugbọn awọn mọ wi pe ẹnikẹni lorilẹede Naijiria lo le e lo ọkọ nla lati fi ko ẹru lati ibi kan si omiran.

Amọ, eniyan kan ti ọrọ naa se oju rẹ sọ wi pe ọkọ nla naa n gbe irẹsi to jẹ ti oloselu kan ni ipinlẹ Ekiti ti oun dije du ipo sẹnatọ ti yoo ma ṣoju ipinlẹ naa nile igbimọ aṣofin agba.

Iroyin ni ìjánu ọkọ naa kọ iṣẹ́ sílẹ̀ tó sì yà lọ bá àwọn èèyàn nínú ọjà naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Twitter ló gbà mí lọ́wọ́ ikú'

Amọ, awọn miiran sọ wi pe awọn ti o ku ninu isẹlẹ naa ju bi o se yẹ lọ, ati wi pe idile wa ninu awọn to padanu ẹmi wọn.