Oyin lé àwọn ènìyàn kúrò l'ábúlé kan ní Plateau

oyin Image copyright Getty Images

Oyin ti le awọn ara abule Gunsun, to wa ni ijọ̀ba ibilẹ Kanam nipinlẹ Plateau kuro niluu.

Idris Mohammed to jẹ Baalẹ abule naa sọ fun BBC pe ni nkan bi aago mejila ọsan ọjọ Aiku, ni awọn deede ri ti oyin ya bo gbogbo abule.

Baalẹ naa fi kun pe loju ẹsẹ si ni gbogbo eniyan ti n sa wọ inu igbo lọ.

''Ọpọlọpọ awọ̀n ara abule to n sa a lọ lo si farapa, ti awọn kan tilẹ kan ni ẹsẹ.''

Fayemi ṣèlérí owó ìtọ́jú àwọn tó fara gbá nínú ìjámba l'Ékiti

Ajọ LASEMA sọ̀rọ̀ lórí okùnfà iná to jó l'Abule Ẹgba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èṣù kìí ṣe sàtànì bí ẹ ṣe máa ń pè é'

Ọkan lara awọn ara abule, Ibrahim sọ pe awọn oyin ọhun ko yọ awọn ẹran ọsin to wa ninu abule silẹ.

Ṣugbọn, awọn ara abule naa n fura pe o ṣeeṣe ko jẹ latara igi nla kan to wa nitosi abule naa ni awọn oyin naa ti jade.

Wọn fi kun pe o ṣeeṣe ko jẹ pe awọn ọmọde to n ṣere nitosi igi naa lo fa wahala naa fun awọn.

Ẹwẹ, awọn kan tilẹ gbagbọ pe o ṣeeṣe ko jẹ oogun ti awọn kan ran si abule naa lo fa a.

Baalẹ abule naa ṣalaye pe iru iṣẹlẹ naa ti aye ri lọdun 1998, to si yọri si iku awọn kan ninu abule.

Related Topics