BBC Nigeria 2019: Ìtàn nípa bí ètò ìdìbò ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Nàìjíríà

Aworan ọlọpaa ati awọn oludibo

Oríṣun àwòrán, FRANCOIS ROJON/AFP/Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọlọpaa n fi apoti ibo han awọn oludibo nilu Eko ninu ibo Aarẹ Naijiria ni 1993

Nilẹ Afrika, Naijiria jẹ orileede kan gboogi nipa oṣelu ati ọrọ aje rẹ.

Naijiria n kopa pataki lawujọ awọn orileede debi wi pe awọn kan ti sọ pe ohun to ba de ba oju Naijiria, yoo kan pupọ orileede ni Afrika.

Fun idi eyi, idibo gbogboogbo to n waye lorileede Naijiria jẹ nnkan ti ọpọ n sọrọ nipa rẹ lafrika ati agbaye.

Gbogbo oju lo ti wa lara Naijiria lati wo bi eto naa yoo ṣe lọ amọ ki a to mọ bi nnkan yoo ṣe ri la ni ki a da ara loye nipa itan eto idibo lorileede Naijiria

Ipilẹ eto idibo

Oṣu Karun, ọdun 1919 ni wọn kọkọ fi eto idibo lelẹ ni Naijiria, lasiko ti ofin asiko naa fi ẹtọ fun diẹ lara awọn ọkunrin ilu lati dibo yan aṣoju mẹta sinu Igbimọ Oluṣakoso ilu Eko.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta , ọdun 1920 si ni idibo akọkọ waye.

L'ọdun 1922, iwe ofin tuntun (Clifford Constitution) jade, eyi to ṣe idasilẹ idibo yan eniyan mẹrin sile aṣofin;mẹta fun Eko, ẹyọkan fun ilu Calabar.

Awọn to si ti pe ẹni ọdun mọkanlelogun tabi ju bẹ ẹ lọ, to jẹ ẹrú ilẹ Gẹẹsi tabi jẹ ọmọ orilẹede Naijiria to ti gbe ni agbegbe kan fun oṣu mejila ṣaaju eto idibo nikan lo ni anfaani lati dibo.

Oríṣun àwòrán, FRANCOIS ROJON/GETTY

Àkọlé àwòrán,

Aworan idibo ọdun 1993

Eniyan bi ẹgbẹrun mẹrin ninu ẹgbẹrun mọkandinlọgọrun to n gbe nilu lo f'orukọ silẹ lati dibo nilu Eko, nigba ti ọtalenirinwo din meje eniyan si f'orukọ silẹ ni ilu Calabar.

Ọdun maarun si ni awọn to ba jawe olubori fi wa nipo.

Eto idibo sile aṣofin waye ni Naijiria lọjọ kejila, oṣu Kejila, ọdun 1959. Ẹgbẹ oṣelu Northern People's Congress lo bori ju pẹlu bi ijoko mẹrinlelaadoje ninu ọọdurun le mejila nile aṣofin ṣe ja mọ ọ lọwọ.

Ọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ, ọdun 1979 ni eto idibo aarẹ kọkọ waye ni Naijiria. Shehu Shagari, ti ẹgbẹ National Party of Nigeria lo jawe olubori. Awuyewuye waye lori esi ibo naa lori, ti ọrọ si de ile ẹjọ to ga ju ni Naijiria. Shagari ni ẹjọ gbè e.

Eto idibo aarẹ tun waye lọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ, ọdun 1983. Shehu Shagari lo tun wọle pẹlu ìdá mẹtadinlaadọta ataabọ ninu ìdá ọgọrun ibo ti awọn araalu di.

Eto idibo

Eto idibo aarẹ tun waye lọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 1993, fun igba akọkọ lẹyin ti awọn ologun ditẹ gbajọba l'ọdun 1983.

Esi ibo naa fihan pe Oloogbe Moshood Kashimawo Abiọla, ti ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP, lo bori. O fi ẹyin Bashir Tofa, ti ẹgbẹ oṣelu National Republican Convention, janlẹ.

Ṣugbọn, olori orilẹede Naijiria nigba naa labẹ iṣejọba awọn ologun, Ibrahim Babangida fagile esi ibo naa. Igbesẹ rẹ naa yọri si rogbodiyan, eyi to tun mu ki iditẹ gbajọba mi i ti Oloogbe Ọgagun Sani Abacha le waju tun waye lọdun naa.

Oríṣun àwòrán, FRANCOIS ROJON/AFP/Getty Images

Àkọlé àwòrán,

MKO Abiola

Eto idibo aarẹ tun waye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 1999. Eyi ni idibo akọkọ to waye lati ọdun 1993 ti awọn ologun ti ditẹ gbajọba.

Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, PDP, lo bori.

Ṣaaju asiko yii ni eto idibo sile aṣofin waye lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 1998. Eyi naa jẹ igba akọkọ ti idibo sile aṣofin waye lati ọdun 1992.

Iditẹ gbajọba ọdun1993 lo si fa a. Gbogbo ẹgbẹ oṣelu to kopa ninu idibo naa lo ni ibaṣepọ pẹlu iṣejọba ologun, ti wọn si f'ofin de awọn ẹgbẹ alatako.

Oríṣun àwòrán, Malcolm Linton/Getty

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ ana Olusegun Obasanjo nilu Eko nibi to ti n kede erongba lati du ipo Aarẹ fun awọn oniroyin lọdun 1998

Ijọba fagile esi ibo yii, eyi si mu ki atundi ibo waye lọdun to tẹle.

Eto idibo mi i tun waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2003. Aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ lo tun bori gẹgẹ bi aarẹ.

Eto idibo gbogboogbo miran tun waye l'ọjọ kẹrinla ati ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2007.

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Eto idibo sile aṣofin ipinlẹ ati ti gomina waye lọjọ kẹrinla, nigba ti ti aarẹ waye lọjọ kọkanlelogun.

Ọsẹ to tẹle ni idibo sile aṣofin apapọ ati ti aarẹ waye l'ọsẹ to tẹle. Umaru Yar'Adua ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo gbegba oroke. Wọn si bura fun l'ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Karun, ọdun 2019.

Awọn onwoye idibo lati inu ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu ṣọ pe eto idibo naa lo buru ju ti awọn ti ti ni gbogbo orilẹede to waye l'aye; ṣiṣe eeru ibo, jagidijagan, jiji apoti ibo gbe ati didẹru ba awọn oludibo.''

Eto idibo gbogboogbo mi i tun waye ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2011. Awuyewuye ti kọkọ waye lori boya ara Ariwa tabi ara Gusu ni ko jẹ aarẹ lẹyin iku Aarẹ Umaru Yar'Adua, to jẹ ara Ariwa.

Oríṣun àwòrán, YASUYOSHI CHIBA/GETTY

Àkọlé àwòrán,

Idibo ọdun 2019 jẹ eleyi ti ọpọ ọmọ Naijiria n foju si lara

Goodluck Jonathan to jẹ aarẹ fidihẹ lẹyin iku Yar'Adua lo wọle sipo aarẹ. Ṣugbọn, lọgan ti idibo naa wa s'opin ni rogbodiyan bẹrẹ ni apa Ariwa.

Eto idibo gbogboogbo to kọja waye ni ọjọ kejidinlọgbọn ati ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2015.

Aarẹ nigba naa, Goodluck Jonathan tun pada dije fun ipo aarẹ, ṣugbọn ko ja mọ lọwọ.

Awọn kan tilẹ sọ pe eto idibo naa lo gba owo to pọju lọ nilẹ Afrika.

Eto idibo naa si ni igba akọkọ ti aarẹ to wa lori aga iṣakoso fidirẹmi ninu eto idibo.