CCT: Adájọ́ fẹ̀yìntì ní àwọn asòfin àpapọ̀ yẹ kó fòǹtẹ̀ lu ìgbẹ́jọ́ adájọ́ àgbà

ile ẹjọ
Àkọlé àwòrán Gbogbo eto ti to ni CCT fun igbejo Adajo Onnoghen

Adajọ fẹyinti Folarinwa Oloyede ti sọ pe gbigbe ti wọn gbe Adajọ agba orilẹede Naijiria, Walter Onnoghen lọ si waju ile ẹjọ to n gbo ẹsun aṣemaṣe awọn to di ipo ilu mu, CCT, ko tọna rara.

Adajọ fẹyinti Oloyede, to ba BBC Yoruba sọrọ lẹyin ti igbimọ CCT sun igbẹjọ naa siwaju, sọ pe ọna kan ṣoṣo lati yọ adajọ agba nipo, ni pe Aarẹ orilẹede Naijiria gbọdọ da laba fun apapọ ile igbimọ aṣofin l'Abuja.

O ṣalaye pe, ida meji ninu ida mẹta ile aṣofin agba l'Abuja gbọdọ faramọ mọ na, ki wọn to le gbe adajọ lọ sile ẹjọ tabi siwaju igbimọ CCT lati jẹjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adajọ fẹyinti Oloyede sọ pe, o ṣe ni laanu pe ajọ CCB ti mọ nipa ẹsun yii lati ọdun 2016, o si kọ lati fẹsun kan adajọ agba Onnoghen to fi di asiko yii.

Ile ẹjọ ọhun ti Danladi Umar jẹ adari fun, ko lee joko ni Ọjọ Aje, nibi ti Adajọ Agba Onnoghen ti tako igbẹjọ rẹ ni ile ẹjọ to n gbẹjọ iwa ibajẹ, CCT.

Umar gbe igbesẹ naa lẹyin ti agbẹjọro fun ijọba, Aliyu Umar fi ọwọ si wi pe ọna ti wọn gba fun agbẹjọro agba Walter Onnoghen ni iwe igbejọ ko tọna rara.

Tani DCP Kayọde Ẹgbẹdokun, ọ̀gá ọlọ́pàá tuntun ní ìpínlẹ̀ Eko?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbìjà: Bàbá mi fi iṣẹ́ ọdẹ ti ń pa lémi lọ́wọ́ ni nítorí babaláwo ni

Adajọ agba naa kọ lati yọju si ile ẹjọ naa, sugbọn ọgọọrọ awọn agbẹjọrọ agba(SANs) lo lọ si ile ẹjọ naa lati se atilẹyin fun agbẹjọro agba naa.

Ṣé adájọ́ àgbà Onnoghen yóò farahàn nílé ẹjọ́?

Ṣe adajọ agba, Walter Onnoghen yoo farahan niwaju ile ẹjọ to n gbọ ẹsun aṣemaṣe awọn to dipo ilu mu lorilẹ-ede Naijiria, CCT ni ibeere ti o n gbẹnu ọpọ onwoye lati igba ti iroyin nipa ẹsun kan ti wọn fi kan adajọ agba naa ni pa kikede dukia rẹ jade sita lopin ọsẹ to kọja.

Oniruuru awọn onimọ, paapaa julọ awọn onimọ nipa ofin ni wọn ti jade ṣalaye pe o ku diẹ kaato, bẹẹni awọn onwoye miran n wii lẹnu pe ko sẹni to kọja ofin.

Kini awọn gomina iha aringbungbun guusu orilẹ-ede Naijiria, (South-South) sọ?

Image copyright Channels tv
Àkọlé àwòrán Ìbéèrè tó ń jẹyọ báyìí ni bóyá adájọ́ àgbà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Walter Onnoghen yóò yọjú sílé ẹjọ́

Ni kete ti iroyin yii ti jade sita ni awọn gomina to wa lati ẹkun aringbungbun guusu orilẹ-ede Naijiria ti wọ inu ipade lọ.

'Ẹ̀ maa ṣe gbagbe pe ẹkun yii ni adajọ agba orilẹ-ede Naijiria, Onnoghen ti wa, ni pato, ọmọ ipinlẹ Cross river ni.

Nigba ti awọn gomina naa yoo si fi jade kuro nibi ipade wọn, abọ ti wọn jẹ faraalu ni ipe si adajọ agba naa pe ko gbọdọ farahan niwaju ile ẹjọ naa.

Awọn gomina naa ni ko dabi ẹni pe aarẹ Buhari ni ọ̀wọ̀ fawọn eeyan agbegbe Niger Delta, eto iṣejọba tiwantiwa ati ẹka iṣedajọ.

Kini awọn agba amofin n sọ?

Image copyright Nigeria Bar Association

Ṣe wọn ni ki sobiya to di egbo, oluganbẹ laa kọ ke si. Awọn agba amofin lorilẹ-ede Naijiria pẹlu ko dakẹ lori ọrọ ọhun o.

Amofin agba, Oloye Afẹ Babalọla (SAN) ni iwa idẹyẹsi iwe ofin orilẹ-ede Naijiria ni igbesẹ lati fa adajọ agba orilẹ-ede Naijiria lọ si ile ẹjọ.

Amofin Afẹ Babalọla ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku ṣalaye pe "ohun ti ofin la kalẹ ni pe ki igbimọ iṣedajọ lorilẹ-ede Naijiria o kọkọ gbọ ẹsun naa ki wọn si ṣe iwadii rẹ ṣaaju igbimọ kigbimọ, nitori naa ko si awijare kankan ninu igbesẹ lati gbe adajọ agba Naijiria lọ siwaju ile ẹjọ CCT" .

Image copyright @Nigerialawyers
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ amòfin ló ní ìgbésẹ̀ náà kò bá ìwé òfin Nàìjíríà mu.

"Bakan naa, iwe ofin orilẹ-ede Naijiria laa kalẹ igbesẹ to yẹ fun yiyọ adajọ agba nipo. Abala 292 (1) (a) (i) ati 292 (1) (b) iwe ofin Nigeria ti ọdun 1999 laa yekeyeke."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMoses Melaye: Dino Melaye sùn ìta gbangba mọ́jú níléesẹ́ DSS

O ni n ṣe ni ijọba n jẹ ko han sawọn ọmọ Naijiria pe nnkan miran wa lẹyin ọrọ ọhun ju eyi to han faraye.

Ẹwẹ, amofin Ẹbun-Ola Adegoruwa pẹlu kin ọrọ naa lẹyin.

O ni awọn ẹsun ti ko bofinmu ni wọn fi kan adajọ agba naa.

"Ninu ẹjọ Nganjiwa ati ijọba orilẹ-ede Naijiria to waye niwaju ile ẹjọ kotẹmilọrun, ko si ẹsun kankan ti a lee fi kan oṣiṣẹ eto idajọ kankan ni ile ẹjọ, ninu eyi ti adajọ agba orilẹ-ede Naijiria wa lai kọkọ gbẹsun naa lọ siwaju igbimọ iṣedajọ orilẹ-ede Naijiria, NJC"

Kini awọn aṣofin n sọ?

Image copyright NAtional Assembly nigeria
Àkọlé àwòrán Awọn aṣofin apapọ pe fun titẹle ilana ti ofin la kalẹ.

Awọn olori ẹka ile aṣofin apapọ mejeeji, ile aoṣofin agba ati ile aṣoju-ṣofin, Sẹnetọ Bukọla Saraki pẹlu aṣofin Yakubu Dogara ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu igbesẹ naa.

Aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Saraki ni igbesẹ ti ofin la kalẹ ni ki ijọba apapọ tẹle lori ọrọ naa.

Saraki ni ifura wa pẹlu ọwọ́ wara-n-ṣeṣa ti wọn fi sare gbe ẹjọ naa kalẹ paapaa nigba ti ọpọ ẹjọ ti wọn ti pe fun ọpọlọpọ oṣu n bẹ nilẹ ti wọn ko fi ọwọ kan.

Bẹẹni Aṣofin Dogara to jẹ olori ile aṣoju-ṣofin ni ẹfọn to ba le eeyan ni furọ lọrọ naa, o n fẹ suuru.

Ki ni Adajọ agba Walter Onnoghen funra rẹ n sọ?

Image copyright Nigeria Bar association
Àkọlé àwòrán Adajọ agba Onnoghen ni oun ko jẹbi

Adajọ agba orilẹ-ede Naijiria, Walter Onnoghen ti sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn ka si oun lẹsẹ lori kikede dukia rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionClaudiah: ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi fínra fún ọpọlọpọ ọdún

Onnoghen ṣalaye ninu iwe awijare to fi sọwọ si ile ẹjọ to n gbẹ ẹsun aṣemaṣe awọn to di ipo ilu mu, CCT pe iyapa to wa laarin fọọmu ikede dukia meji, No. SCN: 000014, ati SCN: 000015, ti oun fọwọ si ko ju pe oun ko tii ṣi awọn aṣuwọn ifowopamọsi naa nigba ti oun buwọlu fọọmu akọkọ ni o jẹ ki oun fi sinu fọọmu keji ti oun fọwọ si .

Pẹlu bi ọrọ seri yii, ibeere ọpọ ni pe, ṣe adajọ agba yoo tẹle ilakalẹ iwe ofin Naijiria ati oun ti awọn amofin agba n sọ pe ko si idi fun un lati fi oju han nile ẹjọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRonke Oṣodi: òótọ́ ọ̀rọ̀ máa ń korò gan ni f'áwa èèyàn