Ìtàn Mánigbàgbé: Alájọ Ṣómólú fi ọdún mẹ́ta gba àjọ láì kọ́ sílẹ̀, kò sì si owó san

Alphaeus Taiwo Olunaike, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí alájọ Sómólú, Image copyright @Dstoryteller

Lọpọ igba ni awọn eeyan maa n pa asamọ pe, ori eeyan kan pe bii alajọ Somolu, to fi ọdun mẹta gba ajọ, ti ko si kọ silẹ, bẹẹ ni ko si owo san.

Fun ọpọ eeyan ati awọn ọdọ aye ode oni, asamọ lasan tabi arosọ ni ọrọ yii, ti wọn ko si gbagbọ wipe ori eeyan kan lee pe to eyi, ti yoo gba ajọ lai kọ silẹ, ti ko si tun ni si owo san.

Sugbọn lootọ ni alajọ Somolu wa, Alphaeus Taiwo Olunaike ni orukọ rẹ, to si gbe aarin wa nilẹ Yoruba, o bimọ, o laya, o kọle, to si tun se awọn ohun rere miran ti eeyan n gbe ile aye se.

Gẹgẹ bi akọsilẹ iroyin loju opo itakun agbaye taa ti ko iroyin yii jọ ti wi, Taiwo Sonaike gbajumọ bii baba alajọ nigba aye rẹ ladugbo Owotutu, Bariga, Awolọwọ, Oyingbo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ohun to se koko to yẹ ko mọ nipa Alajọ Somolu ree:

 • Ọjọ Kẹrindinlogun osu Kẹjọ ọdun 1915 ni wọn bi baba Alajọ Somolu
 • Ẹ̀ta òkò ni Alphaeus Taiwo Olunaike, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí alájọ Sómólú, ìbẹta ni wọ́n bíi
 • Ilu Isọnyin Ijẹbu nipinlẹ Ogun ni iya rẹ, Grace Okuromiko Olunaike ti bii ni ibẹta, ti wọn si fi ọkan rubọ ninu wọn gẹgẹ bii asa igba naa
 • Ile ẹkọ alakọbẹrẹ Emmanuel nilu Ijẹbu Isọnyin ni alajọ Somolu lọ
 • Ọmọ ọdun mẹta lo wa to fi padanu baba rẹ, ti aburo baba rẹ si mu lọ silu Eko
 • Olunaike kọ isẹ aransọ, taa mọ si Taylor, to si fi se isẹ se, amọ owo perete to n ri nibẹ ko to na rara
 • Nigba ti aburo baba rẹ́ yii n lọ fun okoowo ni orilẹede Cameroon ni Taiwo ba tẹle lati wa isẹ kun isẹ rẹ
 • Ilu Cameroon lo ti kọ isẹ ajọ gbigba, to si bẹrẹ isẹ tiẹ ni kete to pada de si ilu Eko lọdun 1954, to si pe orukọ ajọ rẹ ni ‘Alajọ Somolu’
 • Alajọ̀ Somolu ta mọto rẹ lati fi ra kẹkẹ nigba ti isẹ ajọ rẹ buyari, eyi tawọn eeyan fi maa n pa aṣamọ pe ‘ori rẹ pe bii Alajọ Somolu, to ta mọto, fi ra kẹkẹ
 • O kọ ile akọkọ lati idi ajọ̀ to n gba si ojule kẹwa, opopona Odunukan, Ijẹsatẹdo, amọ to ta ile naa fun ijọ kan lẹyin o rẹyin
 • Ile keji ti Alajọ Somolu kọ lo wa ni ojule kẹwa, Ọlọrunkẹmi Owotutu, Bariga nilu Eko
 • Baba Olunaike jẹ akapo fun ijọ Anglika to n lọ ni adugbo Ṣomolu, to tun jẹ akabibeli lasiko isin, taa mọ si ‘Lay-reader’
 • Odu ni alajọ Ṣomolu nigba aye rẹ nidi ajọ gbigba, kii si se aimọ fun oloko lawọn adugbo bii ọja Awolọwọ, Ṣomolu,Ọlalẹyẹ, Oyingbo ati bẹẹ bẹẹ lọ
 • Ẹni ọdun marundinlọgọrun, 95, ni baba Olunaike fẹyinti ninu isẹ ajọ gbigba, lọdun 2010, lẹyin to ti sisẹ takuntakun ninu isẹ ajọ gbigba
 • Alphaeus Taiwo Olunaike jẹ Ọlọrun nipe lọjọ kọkanla, osu kẹjọ ọdun 2012, to si ki aye pe o digbose.

Bi onirese Alphaeus Taiwo Olunaike, taa mọ si Alajọ Ṣomolu ko ba fin igba mọ, eyi to ti fin silẹ ninu isẹ to yan laayo, tii se ajọ gbigba ko ni parun lailai.

O si han gbangba pe, Taiwo Olunaike ko kọja nile aye bii ejo ti ko ni ipa, o ko ipa tirẹ naa si idagbasoke ọmọ niyan, ko mu ọkanmọkan, ko ja ole nidi ajọ to gba, bẹẹ ni ko wa owo ojiji.

Eyi yẹ ko jẹ ẹkọ fun awa naa pe o yẹ ka tiraka lati fi ipa manigbagbe lelẹ ninu isẹ ti a ba yan laayo nitori arise ni arika, arika ni baba iregun, ohun ta ba se loni, ọrọ itan ni yoo da lọla.

Related Topics