Ọba Lamidi Adeyemi pé ọdún 48 lórí ìtẹ́

Image copyright Alafinofficial
Àkọlé àwòrán Aláàfin Ọyọ pé ọdún 48 lórí àpèrè

Òní ló pé ọdún méjìdínláàdọ́ta tí aláfin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹ́ta gori apèrè àwọn bàbá rẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOluwo ti Iwo Ọba AbdulRasheed Akanbi kí Aláàfin Ọyọ kú ọjọ́ ìbí

A bí Lamidi Olayiwola Adeyemi III ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹwàá ọdún 1938.

Oba Adeniran Adeyemi II ní bàbá Lamidi kí wọn to lé kúrò lóri oye fún ibasepọ rẹ̀ pẹ̀lú NCNC.

Lamidi Adeyemi Jọba lẹ̀yìn Gbadegesin Ladugbolu lọdún 1970 lásìkò gomínà Robert Adeyinka Adebayo lẹ́yìn ogun abẹlé Nàìjíríà, bakan naa ní ààrẹ ológun Muritala Ramat Mohammed náà yàn láti kọ́wọ̀ rìn pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Hajj.

Ọpọ̀ àwọn ọmọ kárọ̀ọ̀-oò- jíire ló ti ń kí ori ade kú aṣeyẹ ọdun míràn lórí aléfà, tó fi mọ olori tó kéré jùlọ laáàfin Badirat Adeyemi nígba to lọ sójú òpó instagram rẹ̀ láti lọ kí olówó orí rẹ̀.

Bakan náà lóri atẹ̀jíṣẹ́ facebook ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá ló ti gbóríyìn fún alaafin fun iṣẹ́ ribiribi ti ó ti ṣe lọ́dún méjìdínláàdọ́ta sẹ́yìn, wọn ni Ọba Lamidi ní ó mú aláfíà àti ìtẹ̀síwájú bá Ọyọ

Wọn gbàdúrà kí ọlọrun fún baba ní ẹ̀mí gígùn lórí ilẹ̀

Related Topics