Arm forces Remeberance day: Naijiria ń ṣe ìrántí àwọn ológun to ṣubú lójú ogun

Awọn ọmọ ogun Naijiria to ti lọ Image copyright SODIQ ADELAKUN/AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán ọpọ ọmọ ogun Naijiria lo ti fẹmi wọn silẹ

Òní ni àyájọ́ ọjọ́ àwọn ọmọ ogun tói ṣègbé sójú ogun ní Naijiria, àwọn àwọran bí iranti naa ṣe ń lọ ati oun ti àwọn ọmọ Naijria n sọ rèé.

Àwọn ẹgbégun Naijiria gbalejo Aarẹ Muhammadu Buhari ni Eagles Square fun ayajọ ọjọ naa.

Image copyright Bashir Ahmad
Àkọlé àwòrán Iṣe ologun buyi kun eniyan lawujọ

Buhari naa yan bi oloogun gẹgẹ bii olori ogun Naijiria.

Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin Agba Bukola Saraki ati abẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin Kekere, Yakubu Dogara, naa juba awọn ọmọ ogun to ti ṣegbe ni Eagles Square.

Image copyright Bukola Saraki
Àkọlé àwòrán Awọn oloṣelu gan mọ riri awọn ọmọ ogun

Saraki gbori yin fun awọn obirin ati ọkunrin to n fi ẹmi wọn daabo bo ọmọ Naijiria.

Gomina Ipinlẹ Kaduna, Nasir el-Rufai na ko gbẹyin. O sẹ ẹyẹ fun awọn ọmọ ogun to ti re kọja naa.

Image copyright NASIR EL RUFAI
Àkọlé àwòrán Aabo ẹmi ati adukia ara ilu lo jẹ wọn logun
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption2019 Elections: Aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ni ìjíròrò Eko yóò bẹ̀rẹ̀

Ni Ipinlẹ Delta, Gomina Ifeanyi Okowa naa ṣe iranti awọn ọmọ ogun.

Àwọn oludije fun ipo Aarẹ bii Oby Ezekwesili na ṣe sàdáńkátà sí àwọn ọmọ oloogun.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí: