Brexit: Ọ̀rọ̀ kò yé wa mọ́!

EU and UK flags pointing in opposite directions Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Brexit? Awon wo lo kan?

Ni ọjọ Isegun, awọn aṣofin Ilẹ Gẹẹsi n dibo lori ipinnu adari ijọba, Theresa May lati ko orilẹ-ede naa kuro ninu ajọ European Union.

Idibo naa ti wọn sun siwaju lati ọjọ kọkanla, oṣu kejila, ọdun 2018 lo n ka wakati igba ti orilẹ-ede naa yoo dagbere fun EU ni ọjọ kọkandinlọgbọn, ọsu kẹta.

Ko si ẹnikẹni to mọ oun ti Brexit yoo ja si, ọrọ naa si le ma fori sibi kan titi opin ọsẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀rọ̀ lórí Brexit

Ṣugbọn oun ti a le mọ lakọkọ ni bi awọn aṣofin ṣe le gbogun ti awọn adehun ti Theresa May ni pẹlu EU ati pe boya o tilẹ ni eto kankan lori ọrọ naa.

Eyi ko daju nitori pe, ti o ba ja kulẹ ninu idibo naa ni ọjọ Isegun, o gbọdọ sọ fun awọn aṣofin ni ọjọ Aje to tẹle oun ti o n gbero lati ṣe.

Kini oun ti wọn tilẹ n dibo le lori gan?

Adehun Theresa May pẹlu EU lori Brexit pin si meji, ipinnu ti ofin de nipa kikuro ninu EU tabi ipinnu ti ofin ko de.

Awọn aṣofin to fẹran Brexit ninu ijọga May ni adehun naa ti jẹ ki Ilẹ Gẹẹsi sun mọ EU just ṣugbọn awọn alatako wọn ni alaye adehun naa ko ye ara ilu daradara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOduduwa Alphabet: òmìnira èdè ti dé fún Port Novo báyìí

Ki lo maa ṣẹlẹ bayii?

BBC ni o ṣeeṣe ki ipinnu May nijakule ti wọn ko ri iru rẹ ri ni ọgọrun un ọdun. Oun ati awọn ti wọn jọ n ṣe ijọba yoo maa sare lati jẹ ki ijakulẹ naa mọ niwọnba.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Cbocbo oju wà lára Theresa May bayii

Ki ni Theresa May yoo ṣe to ba ni ijakulẹ

Awọn ti o n ba May ṣiṣẹ ni awọn gan ko mọ oun ti olori ijọba naa yoo ṣe to ba ja kulẹ.

Ni gbangba ati ni ikọkọ, May ni ipinnu oun dara ati wipe oun nikan ni ọna ti ilu ko fi ni bajẹ.

Awọn oun to le ṣẹlẹ rèé: pada si EU lati jẹ ki awọn adehun to sẹ pẹlu ajọ naa jẹ oun ti awọn aṣofin fẹ, ko sọ fun awọn aṣofin ki wọn ba oun wa ọna miiran to yatọ si adehun oun, tabi ko tilẹ halẹ mọ wọn.

Ki lo n ṣẹlẹ pẹlu ẹgbẹ alatako?

Ki i ṣe ẹgbẹ oṣelu Conservative ni ko ni iṣokan lori ọrọ Brexit, ọrọ ẹnu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour naa ko ko lori ọrọ naa.

Awọn olori Labour labẹ iṣakoso Jeremy Corbyn fẹ Brexit, ṣugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ fẹ ki Ilẹ Gẹẹsi ṣe dibo itagbangba (referendum) ẹẹkeji lati jẹ ki orilẹ-ede naa duro sinu EU.

Ẹgbẹ oṣelu Labour ti ni awọn ko ni dibo fun adehun May lori Brexit.

Image copyright Getty Images

Ki lo wa maa ṣẹlẹ lori Brexit?

Ko sẹni to mọ.

Lẹyin ọdun meji ati aabọ, ẹnu awọn aṣofin ko tii ko lori esi idibo itagbangba to waye lorilẹ-ede naa.

Ko si ọrọ oṣelu to buru to yii lati ọdun 1945.

Àwọn iròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí: