2019 Election: INEC sòfin láti dènà fífi owó ràbò níbi ìdìbò 2019

Ibudo idibo
Àkọlé àwòrán 2019 Election: INEC sòfin láti dènà "SEE & BUY" níbi ìdìbò 2019

Àjọ elétò ìdìbò Nàìjíríà, INEC tí ṣe àgbéjáde àwọn òfin àti àlàsílẹ̀ tuntun láti dènà owó pínpín níbi ìdìbò gbogboogbò ọdún 2019.

Nínú ìwé ofin túntun náà ní wọn ti sàlàyé pé, àti ẹ̀rọ tí wọn fi ń yẹ káàdì ìdìbò wò àti káàdì ìdìbò, ní àwọn yòó lò fún ètò ìdìbò.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOduduwa Alphabet: òmìnira èdè ti dé fún Port Novo báyìí

Ìwé ọ̀hún pẹ̀lú ló kéde àsìkò ìdìbò ààrẹ, àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà tí yòó wáyé ní ọjọ kẹrìndínlógún oṣù kejì ọdún, 2019, bákàn náà ló fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, àwọn ìbò gómìnà àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìbílẹ̀ yóò wáyé lẹ́yìn òsẹ̀ méji.

Àwọn ǹkan míràn tó tún wà nínú ìwé òfin náà:

  • Gbogbo éni tó bá jẹ́ ọmọ Nàìjíríà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti dìbò níwọ̀n ìgbà tí orúkó bá ti wà nínú ìwé àkọ́sílẹ̀ tí o sì mú káàdì ìdìbò rẹ dáni.
  • Gbogbo àwọn ààyè ìdìbò ní yóò ní ààbo tó péye, sùgbọ́n ìbi tó ba wà ní ìta gbangba, ààye yóò wà fún àwọn alábọ̀ọ̀ ara.
  • Ní ṣíṣẹ̀ ń tèlé bí àwọn ba ṣe fi orúkọ sílẹ̀ lọ́jọ́ ìdìbò ní ìdìbọ yóò ṣe wáye
  • Kò ní sí ààye fún ẹníkẹ́ni láti díbò ní ibi tí kò bá ti fí orúkọ sílẹ̀ tàbí ibi tí ó yàtọ̀ sí ààye tí INEC pa láṣẹ fún láti dibò.
  • Àago mẹ́jọ ààrọ̀ ní ìforúkọsílẹ̀ àti ìdìbò yóò bẹ̀rẹ̀ tí yóò sì parí ní ààgo mejì ọsán, bákan náà gbogbo àwọn oludibò tó bá ti wà lóri ìlà ní ààgo méjì ní yóò dibò
  • Lásìkò ìforúkọ sílẹ̀ wọn ó kọ́ka yẹ káàdì ìdìbò wò láti ríì dájú pé kìí ṣe ayédèrú, bákan náà ní wọn ó yẹ ìka wo àti orúkọ náà nínú ìwé akọsílẹ̀ láti mọ kí ẹni náà tó tika bọ ọdà.
  • Ní deédé ààgo mẹ́jọ àwọn àlabojúto ètò ìdìbò yóò fààyè gba olùdìbò láti wọlé, wọn ó sì kédé àwọn òṣìsẹ́ elétò ìdìbò, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn alábajúto míràn tó ba wà níbẹ̀.
  • Wọn ó fún àwọn aboyún, arúgbó àti àwọn aláàbọ̀ ara lánfàní láti kọ́kọ́ dìbò.