2019 elections: Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀ rọ àwọn olóṣèlú láti ṣọ́ra ṣe fún ìdìbò ọdún 2019

Atiku n ki Ọọni Image copyright Yera Moses
Àkọlé àwòrán Ọọni ni orilẹede Naijiria tobi ju ilepa oloṣelu yoowu lọ

Lori idibo 2019, Ọọni ile ifẹ, Adeyẹyẹ Ogunwusi, Ọjaja II ti ke sawọn oloṣelu lorilẹ-ede Naijiria lati fi alaafia, idagbasoke ati igbayegbadun Naijiria ṣaaju ninu ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe.

Amọran yii ni Ọọni Ogunwusi gbe kalẹ lasiko ti oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Abubakar Atiku bẹẹ wo ni aafin rẹ nilu Ile Ifẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atiku wa ni ipinlẹ Ọṣun ni ọjọ Iṣẹgun lati polongo idibo fun erongba rẹ lati du ipo aarẹ lasiko idibo apapọ ọdun yii.

"Orilẹ-ede Naijiria ni a gbọdọ maa fi ṣiwaju ninu ohun gbogbo nitori ọrọ Naijiria ju ilepa ẹnikẹni lọ."

Image copyright yera moses
Àkọlé àwòrán Ọọ̀ni Ogunwusi ní àláfíà Nàìjíríà ju ìlépa àwọn olóṣèlú lọ.

"Bi o tilẹ jẹ pe a n mu idagbasoke ba orilẹ-ede Naijiria bayii, sibẹ omi ṣi pọ lamu paapaa julọ nipa yiyago fun oṣelu onijagidijagan, yala gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba ni o tabi ẹgbẹ oṣelu alatako."

Ninu ọrọ rẹ, Atiku Abubakar to kọwọrin pẹlu iyawo rẹ, Titi Abubakar ni ọla ati ọwọ ti oun ni fun Ọọni Ile Ifẹ lo jẹ ki oun kọkọ wa foribalẹ niwaju rẹ naa ki oun to mu ohunkohun ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWoli Kasali: Angẹli mi ni orékelẹ́wà Dọlapo Awoṣika

Lara awọn to ba Atiku Abubakar kọwọrin, ni alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Uche Secondus, gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun, Ọlagunsoye Oyinlọla atawọn eekan ẹgbẹ oṣelu naa miran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé