e-Passport: Ààrẹ Buhari tẹ́wọ́ gba ìwé ìrìnnà Nàìjíríà tuntun

Buhari n ṣe ayẹwo fun iwe irinna tuntun naa Image copyright Bashir Ahmad
Àkọlé àwòrán 'iwe irinna tuntun naa ko fopin si elo ti iwe irina to wa tẹlẹ.'

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣefilọlẹ iwe irinna silẹ okeere tuntun, e-Passport oni saa ọdun mẹwa ti wọn ṣẹṣẹ gbe jade.

Ọga agba ileeṣẹ to n mojuto iwọle-wọde lorilẹ-ede Naijiria, NIS Mohammed Babandele ṣalaye fawọn oniroyin pe awọn amuyẹ kan jẹyọ lara iwe irinna tuntun naa ti yoo mu ki o rọrun fun eto aabo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Amuyẹ eto aabo to peye wa ni ara rẹ ni eyi ti yoo daabo bo awọn ọmọ Naijiria to ba n lọ si oke okun ki wọn lee maa de ileeṣẹ aṣoju ijọba Naijiria nilẹ okeere to ba wu wọn."

O ni ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn naira ni wọn n ta iwe irinna oloju iwe mejilelọgbọn, ati pé ẹgbẹrun marundinlogoji ni toloju iwe mẹrinlelọgọta ti o jẹ ọlọdun marun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWoli Kasali: Angẹli mi ni orékelẹ́wà Dọlapo Awoṣika

O ni ẹgbẹrun lọna aadọrin naira ni wọn n ta iwe irinna oloju iwe mẹrinlelọgọta ti wọn ṣẹṣẹ ṣe jade naa.

O ni agbejade iwe irinna tuntun naa ko fopin si lilo ti iwe irinna to wa tẹlẹ.Ati pé ọdun mẹwaa ni yoo jẹ gbendeke fun lilo tuntun.