Sarumi Ni obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò gbégbá ipò gómìnà l'Ọyọ

Ọmọbọlanle Image copyright Bolasarumialiyu
Àkọlé àwòrán Oun ni obìnrin àkọ́kọ́ tó ń dupò gómìnà ní ìpínlẹ̀ ọyọ

Ojoojumọ kọ ni a n gbọ pe obinrin n dupo gomina ni ipinlẹ Ọyọ, lati igba ti wọn ti da ipinlẹ naa silẹ ni ọdun 1976.

Arabinrin Omobolanle Sarumi Aliyu ni obinrin akọkọ ti yoo jade lati dije ipo gomina ipinlẹ Ọyọ.

A bii ni ọjọ kejilelogun oṣù kẹta, ọdún 1979, nibi ọdun mẹta lẹyin ti wọn da ipinlẹ naa silẹ. Ọmọ ilẹ Gẹẹsi ni Iya rẹ, baba rẹ Ali Balógun Sarumi si jẹ ọmọ ile Oluyọle.

Image copyright Bolasarumialiyu/Instagram
Àkọlé àwòrán Ọmọ bíbí ìlú Ibadan ni

Ilẹ Ibadan lo ti kawe alakọbẹẹrẹ, ati girama , ko to gba Fasiti Anglia Ruskin Cambridge, ilẹ Gẹẹsi lọ fun iwe giga.

O ti fi igba kan jẹ oluranlọwọ pataki fun Minisita olu ilu Naijiria , Oloye Jumoke Akinjide , o si ti bẹrẹ oṣelu lati igba naa pẹlu ẹkọ to kọ lara baba rẹ.

Image copyright Bolasarumialiyu/Instagram
Àkọlé àwòrán Ọmọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni Ìyá rẹ̀

Abẹ ẹgbẹ oṣelu Nationla Interst Party (NIP) ni arabinrain naa ti n dije gẹgẹ bi gomina.

O ni afojusun ohun ni lati mu igbe aye irọrun ba awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ, ati la ọna to tọ ninu oṣelu lorilẹede Naijiria .