Tunde Bakare: Ọmọ Nàíjíríà, ẹ gbáradì fún àgbékalẹ̀ Nàíjíríà tuntun

Pasitọ Tunde Bakare Image copyright @T_Bakare

Olusọ̀ aguntan agba fun ijọ Latter rain Assembly, Pasitọ Tunde Bakare ti kesi awọn ọmọ Naijiria to fẹ agbekalẹ orilẹede Naijiria tuntun lati darapọ mọoun fun ijagudu fun agbekalẹ orilẹede Naijria tuntun.

Pasitọ Bakare pe ipe yii lasiko to n bawọ̀n ọmọ Naijiria sọrọ lori ipo ti orilẹede yii wa lọwọ-lọwọ bayii, eyi to se lasiko isin ọjọ isinmi ninu ijọ rẹ.

Bakare ni lasiko ipalẹmọ fun eto idibo yii, Buhari ti n salaye ohun to se lati daabo bo Naijiria ati ọna ti wọn fẹ gba gbe Naijiria lọ si ipele to kan, ti Atiku Abubakar naa si ti n bu ẹnu atẹ lu awọn aseyọri yii, to si pinnu lati se atunto ẹka eto isejọba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakare tun wa bu ẹnu atẹ lu irinajo ti oludije fẹgbẹ oselu PDP naa rin lọ silẹ Amẹrika, pẹlu afikun peeyi gan lo jẹ logun.

"Nibayi ti Atiku ti de lati Amẹrika, yoo joko bayi lati koju isejọba, ki ni lilọ Amẹrika nii se pẹlu atiku. O fihan pe ko fẹ si iyatọ laarin Atiku ati Buhari nitori awọn mejeeji dijọ n wa ohun ti ko sọ̀nu kiri ni."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mi o fẹẹkan ni mo fẹ dupo aarẹ'

Pasitọ agba fun ijọ Latter Rain naa ni laarin awọn ọdọ to fẹ se aarẹ lorilẹede yii, ko si eyi to ni ọgbọn agba to Oby Ezekwesili, tii se oludije ACPN.

"Ọlọpọlọ pipe, to ni ilana isejọba to pegede ati eto Ọlọrun fun Naijiria ni Ezekwesili. Mo kan saara si pe o jade lati du ipo aarẹ, mo si mọ pe pẹlu jijade rẹ ati awọn oluidije yoku to jẹ ọdọ, ko si ẹni ti yoo sọ mọ lẹyin idibo pe, ko si oludije to pegede lasiko ibo naa.

Bakare ni ọrọ oun ko nii se pẹlu atilẹyin fun oludije kankan, amọ ohun ti Naijiria nilo ni ikọ oloselu ti yoo mu atunto ba ilẹ yii, ti ko ni jẹ alajẹbanu, ti yoo sisẹ pẹlu ẹka alasẹ ati asofin lati mu isọkan ba ilẹ yii.

O fikun pe o wa wa lọwọ ileesẹ aarẹ lati sawari awọn ikọ alatunto yii, eyi to pe ni ‘Team Restructuring’.

Image copyright @T_Bakare

Tunde Bakare tun sọrọ lori eto atrunto il yii ati ileri awn oludije aar kọọkan lati mu Naijiria de ebute ogo.

"Ohun to jẹ ki n gba lati dije bii igbakeji fun Buhari tẹlẹ ni eto atunto Naijiria to mu ni ọkunkundun nigba naa, eyi ti ileesẹ aarẹ ni ko se koko mọ̀ bayii."

O ni idi ti oun fi se agbekalẹ ikọ Save Nigeria Group (SNG) ree, eyi to kun fun awọn ọlọpọlọ pipe awọn ọmọ ilẹ yii.

Bakare tun gbadura pe, ko to di ọjọ Kẹrindinlogun osu Keji ọdun 2019, ki oluwa fi iji lile gba awọn ọta Naijiria kuro, ki omirira lee ba orilẹ́ede yii lọwọ awọn amunilẹru.

Tunde Bakare, ẹni to tun kesi awọn ọmọ ogun orilẹede Naijria lati dẹkun yiyaju sawọn araalu, tun rọ wọn lati maa se isẹ wọn tọwọ tọwọ.

Image copyright @T_Bakare

A gbọdọ maa se iranti awọn ologun to ti ku soju ogun, ka si mase gbagbe awọn ẹbi wọn.

Iku wọn ko gbọdọ ja sasan nipa sise agbekalẹ isejọba rere eyi ti wọn ku fun.

O ni bi awọn ọmọ ogun Naijiria se n se ojo lo yẹ ka fi bi ara wa leere pe ohun ija taa lo ni agbara ju laarin awn ologun Naijira ati awọn adunkooko mọni.

Nigba to n beere pe iru orilẹede wo lo yẹ ki eeyan fi ẹmi rẹ lelẹ fun, Bakare ni ko sẹni ti yoo fi ẹmi rẹ lelẹ fun orilẹede ti ko lee san owo osu to yẹ fawọn ologun atawọn osisẹ rẹ, tawọn oloselu rẹ si n gba owo gọbọi.

Image copyright @T_Bakare

O fikun pe, orilẹede ti eto ẹkọ rẹ́ ti dẹnu kọlẹ, ti awọ̀n akẹkọ ati olukọ si joko sile fun ọjọ pipẹ, ko yẹ ni eyi ti eeyan ku fun.

Pasitọ Bakare wa tọka si orilẹ ede ti eeyan lee ku fun bii:

 • Orilẹede ti yoo lee pese awọn ohun eelo amayedẹrun to yẹ bii ipese irinna oju irin
 • Orilẹede ti yoo lee pese eto ilera to se koko, ti awọn eeyan orilẹede naa ko si ni maa ku bii adiẹ, paapa lasiko ibimọ
 • Orilẹede ti yoo lee daabo bo ara rẹ ati awọn eeyan inu rẹ, paapa awọn eeyan rẹ loke okun, ti wọn ko fi ni maa pa wọn nipakupa
 • Orilẹede ti eto iselu rẹ duro re, ti iwa jagidijagan ko ni gba ilẹ kan, tawọn oloselu ko ni maa jija gidu lati jẹ ohun alumọọni rẹ ni ijẹkujẹ

Bakare ni nitori pe orilẹede Naijria ko se ku fun, ni awọn ọmọ Naijiria se setan lati ta kaadi idibo wọn, tori ko si ohun iwuri kankan to lee mu ki wọn fi ẹmi wọn lelẹ fun ilẹ baba wọn.

Ojisẹ Ọlọrun naa wa n rọ awọn ọmọ ilẹ yii pe, ireti si wa fun wa ni orilẹede Naijiria, to si se agbekalẹ iru orilẹede ti Naijiria yoo jẹ lọjọ iwaju bii eyi:

 • Naijiriaa yoo jẹ eyi ti ẹkun gbogbo to wa lorilẹede yii yoo ti wa ni isọkan
 • Orilẹede yii yoo jẹ orilẹede ti yoo setọju awọn eeyan rẹ, ti awọn eeyan yoo si mọ ipa orilẹede wọn lara si rere
 • Orilẹede ti yoo ni idagbasoke ọrọ aje to pedege, tawọn ohun alumọni bii eto ọgbin ati ipese ohun amayedẹrun yoo si fidi mulẹ
 • Orilẹede ti yoo mu ilera to peye wa fawọn eeyan rẹ, ti idagbasoke yoo si wa fun awọn awọn eeyan, ti awọn ẹka eto ẹkọ yoo si maa se amulo awọn ohun alumọni ilẹ yii lati mu ki eto ẹkọ ati ọmọniyan dangajia
 • Orilẹede ti a maa lo afẹfẹ gaasi ati oorun lati fi pese ohun eelo amusagbara, eyi ta tun maa fi ransẹ sawọn orilẹede alamuleti wa, ti ibi gbogbo yoo si mọlẹ laisi okunkun ni Naijiria
 • Naijira yoo jẹ ibi ti aparo kan ko ti ni ga ju ọkan lọ, tawọn agbofinro wa yoo si mọ pe awọn kan wa ti yoo bi awọn, ti awọn ba siwahu, ti ẹmi eeyan yoo si se iyebiye
 • Naijiria ta fi n la ala yoo bọwọ fun ofin, ti eto idajọ yoo si fiidi mulẹ, ti ọwọ nla yoo si wa fun iwe irinna wa loke okun
 • Naijiria ti yoo ni ẹka ọmọ ologun ti yoo fidi mulẹ, ti yoo si pẹka de ibi gbogboo lati pese eto aabo to peye fun orilẹede wa ati awn aladugbo wa pẹlu
 • Ti gomina yoo ti jẹ alakoso eto aabo ni ipinlẹ rẹ nitootọ, lai sọ lori ahọn lasan.
 • Orilẹede ti awọn ologun yoo ti ni iwuri lati fi ẹmi wọn lelẹ fun orilẹede Naijiria.

Lẹyin idibo 2019, orilẹede naijiria ni yoo si papa bori lai naani ẹgbẹ oselu to moke tabi fidi rẹmi.

O wa kesi awọn oludije fun ipo aasrẹ lati fọwọ sowọpọ sugba ẹni to ba wọle alti gbe Naijiria goke agba lati se agbekalẹ Naijiria tuntun.