Olusegun Obasanjo: Ìjọba Ààrẹ Buhari kò yàtọ̀ sí ti Abacha

Obasanjo-Zakari Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ní ilé rẹ̀ ní Oke-Mosan, OOPL ,Abeokuta ni ààrẹ tẹ́lẹ̀rí náà ti bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ lọ́jọ́ Àìkú lórí ipò tí Naijiria wà.

Aarẹ tẹlẹri Olusegun Obasanjo, ti rọ osisẹ Ajọ INEC Amina zakari lati kọwe fi ipo rẹ silẹ gẹgẹbi kọmisọnna gbogboogbo fun Ajọ INEC ninu idibo 2019.

Ọbasanjo ni ti ko ba fi ipọ rẹ silẹ, yoo soro lati ri osisẹ ajọ eleto idibo naa gẹgẹbi ẹni to kunjuwọn fun idibo ọdun 2019, ti kii si se wi pe ijọba to wa lode fẹ lo Amina Zakari lati da oju ibo ru lasiko ibo.

O fikun wi pe ti ko ba fipo rẹ silẹ,a jẹ wi pe wọn fẹ lo o lati yii ibo ati lati tẹ ika lọna ẹburu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAmina Zakari: Ojúṣe mi kìí ṣe láti ka ìbò

Ọpọlọpọ awuyewuye lo wa lori iyansipo Amina Zakari,ẹni ti iroyin sọ wi pe o jẹ ibatan aarẹ Buhari, amọ Zakari sọ wi pe oun ko tan mọ aarẹ Buhari lọna kankan.

Ìjọba Ààrẹ Buhari kò yàtọ̀ sí ti Abacha

Aarẹ tẹlẹri Olusegun Obasanjo, ti fi ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari we ti ijọba ologun ti ọgagun Sani Abacha to fi aye ni awọn eniyan nigba aye rẹ.

Ọbasanjo sọ eyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ile rẹ to wa ni Abeokuta ni ipinlẹ Ogun.

Image copyright @dondekojo

Nigba to n fi ijọba Buhari we ti Sani Abacha, Ọbasanjọ ni o yẹ ki awọn ọmọ Naijiria dide lati se ohun ti wọn se lasiko ijọba Abacha, to fi mọ awujọ agbaye pẹlu.

Bakan naa, O ni oun ko ni igbagbọ ninu Ajọ INEC lati se eto idibo ti yoo muna doko ni idibo gbogboogbo ti yoo waye ni 2019.

Obasanjo ni idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Osun ko nilo atundi idibo to waye lawọn agbeegbe kan, amọ O ni nitori ijọba to wa lode ni Ajọ INEC fi gbe igbesẹ naa, eyi ti o mu ki APC o wọle sipo gomina ni ipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, o fikun wi pe orẹ oun to sun mọ ọga agba Ajo Inec fi oun lọkan balẹ wi pe ohun gbogbo yoo lo ni iroworose, amo baba obasanjo ni opo oro ko kun agbon ni oro naa ri, ati wi pe ki ajo inec o fi ododo leke ni idibo gbogboogbo naa.

Image copyright @OOFoundation

Ọbasanjọ fikun pe orilẹede Naijiria nilo olori ti ọpọlọ rẹ ji pepe, ti ilera ara rẹ si dangajia pipọ.